Faith Adebọla, Ogun
Apo simẹti meje, ti iye rẹ to ẹgbẹrun mọkanlelọgbọn Naira, taati-wan taosan (N31,000) tawọn ọdaran meji kan, Dada Lekan, ẹni ọgbọn ọdun, ati Wasiu Salaudeen, ẹni ọdun mejilelogun, ṣe afọwọra rẹ ti sọ wọn di agbalẹ ilu, ile-ẹjọ ti paṣẹ pe ijiya ẹṣẹ wọn ni kawọn mejeeji ki igbalẹ mọlẹ, ki wọn gba tinu-tode ọgba ile-ẹjọ naa ko mọ fefe fun ọsẹ kan gbako, gẹgẹ bii ijiya ẹṣẹ wọn.
Onidaajọ A. O . Adeyẹmi, ti ile-ẹjọ Majisreeti kan to fikalẹ siluu Ọta, nipinlẹ Ogun, lo gbe idajọ naa kalẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ogunjọ, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.
Gẹgẹ bii alaye ti Agbefọba, Inpẹkitọ E. O. Adaraloye, ṣe ṣalaye ni kootu, o ni ileeṣẹ ti wọn ti n ta simẹnti, Popoọla Ọlawale Investment Company, to jẹ ti Ọgbẹni Popoọla Ọlawale, eyi to wa laduugbo Ijaba, niluu Ọta, lawọn ọdaran mejeeji ọhun ti n ṣiṣẹ, wọn n ba wọn taja nibẹ, amọ lọjọ kejilelogun, oṣu Kejila, ọdun to kọja yii, niṣe ni apo simẹnti meje ṣadeede dawati pẹlu simẹnti inu ẹ, wọn wa a titi wọn ko ri i.
Wọn beere bọrọ naa ṣe jẹ lọwọ Lekan ati Wasiu, wọn lawọn mejeeji ko ri alaye gunmọ kan ṣe, kantan-kantan ni wọn n sọ.
Lẹyin iwadii laṣiiri tu pe awọn ni wọn ji simẹnti ọhun, Wasiu ji baagi mẹta, Lekan si ji baagi mẹrin, wọn ta a fawọn birikila kan tawọn yẹn o mọ pe niṣe ni wọn ji wọn, wọn si da owo ẹ sapo, eyi lo mu ki ọga wọn fọlọpaa ko wọn, ti wọn fi dero kootu lẹyin ti wọn ti sun atimọle fọpọ ọjọ.
Ẹsun ole jija ati igbimọ-pọ lati huwa buruku, eyi to ta ko isọri irinwo din mẹwaa (390) iwe ofin iwa ọdaran nipinlẹ Ogun, ni wọn fi kan wọn, awọn mejeeji si gba pe awọn jẹbi loootọ. .
Ladajọ ba paṣẹ pe ki wọn mọ bi wọn ṣe maa da ẹgbẹrun mọkanlelọgbọn o le ọgọrun-un kan Naira owo simẹnti ti wọn ji pada, ki wọn si gbalẹ kootu fọsẹ kan, ki gbogbo aye ri wọn, koju le ti wọn. O loun feyi fa wọn leti ni o, tori ko si akọsilẹ pe wọn huwa ọdaran bẹẹ ri, aijẹ bẹẹ, sẹria wọn iba nipọn ju bẹẹ lọ.