Ẹgbẹ PDP ati APC sọko ọrọ sira wọn nitori bi Fayemi ṣe ti ileewe pa fun ọsẹ meji l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ẹgbẹ Alaburada (PDP) ati ẹgbẹ Onigbaalẹ (APC) ni wọn ti n sọrọ kobakungbe sira wọn nipinlẹ Ekiti ni lori bi Gomina ipinlẹ naa Dokita, Kayọde Fayẹmi ṣe paṣẹ pe ki wọn ti gbogbo ile-iwe girama ati ti alakọọbẹrẹ to jẹ tijọba ati ti aladaani pa nipinlẹ naa.

Ti ẹ ko ba gbagbe, lati ọsẹ kan sẹyin ni gomina ipinle naa ti paṣẹ pe ki wọn ti gbogbo ileewe to jẹ tijọba pa nipinlẹ naa lati faaye silẹ fun ayẹyẹ ọdun asa ati iṣe ( National Festival of Arts and Culture) SAFEST.

Ninu iwe kan ti Alukoro fun eto iroyin fun ẹgbẹ PDP nipinlẹ naa, Ọgbẹni Raphael Adeyanju, ko lẹyin ipade igbimọ ẹgbẹ naa to waye ni ọfiisi ẹgbẹ naa to wa niluu Ado-Ekiti, juwe ẹgbẹ APC gẹgẹ bii ọta ilọsiwaju fun eto ẹkọ.

Ipade naa ti Adele alaga ẹgbẹ naa, Ọnarebu Lanre Ọmọlaṣẹ, wa nibẹ juwe igbesẹ gomina naa gẹgẹ bíi oun to buru, ti ko si ni idi pataki.

O sọ pe o jẹ ohun ti ko bojumu buru gidigidi pe awọn ọmọ ileewe to jẹ ẹyin ọla awọn obi wọn jokoo sile fun ọsẹ meji gbako nitori ayẹyẹ ti ko nidii.

Ẹgbẹ naa sọ pe loootọ ko si oun to buru nibẹ lati ṣe ayẹyẹ ọdun aṣa ati ti ibilẹ, ṣugbọn igbesẹ Gomina Fayemi lati da gbogbo akẹkọọ duro sile fun ọsẹ meji ni ko dara rara.

Won ṣalaye pe gomina ti kọkọ ṣeleri pe oun yoo da aṣa ati ohun ibilẹ wa to ti sọnu sẹyin pada fun wa nipinlẹ naa lasiko to n ṣe ipolongo ibo ni ọdun mẹta sẹyin.

Ẹgbẹ PDP ni eto ẹkọ to jẹ ohun amuyangan fun gbogbo ọmọ ipinlẹ Ekiti ni ẹgbẹ Onigbaalẹ ti da oju rẹ bolẹ fun odidi ọsẹ meji nitori ayẹyẹ ti wọn n ṣe, ati pe ẹgbẹ naa ko bọwọ fun eto ẹkọ.

” Awa ko mọ idi pataki ti ijọba kan yoo fi da gbogbo eto ẹkọ duro lati alakobere titi de girama titi de ile-iwe aladaani fun ọsẹ meji nitori pe ipinlẹ naa n gbalejo ayẹyẹ idije fun asa ati ibilẹ.”

Nigba to n fesi si ọrọ naa, Alukoro ẹgbẹ APC nipinle Ekiti, Ọgbẹni Ṣẹgun Dipẹ, sọ pe ọsẹ kan pere ti ijọba kede titi gbogbo ileewe pa waye lati ma jẹ ki awọn akẹkọọ sa jade nileewe wọn lasiko ti awọn oludije fun eto naa wa ni awọn ileewe ati ile igbafẹ nipinlẹ naa.

Dipẹ juwe ọrọ ti ẹgbẹ PDP sọ yii gẹgẹ bii ohun ti ko wulo, ati ohun to ti kọja, o ṣalaye pe ko si gomina kankan ni orilẹ-ede Naijiria to fẹran eto ẹkọ bii Fayemi, o ni eyi lo fa a ti gomina yii ṣe ṣe igbekalẹ eto ẹkọ-ọfẹ lati ileewe akọọbẹrẹ titi de girama, to si da gbogbo owo ti wọn n gba lọwọ wọn duro lọgan.

Leave a Reply