Monisọla Saka
Oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar, ti sọko ọrọ si ẹgbẹ oṣelu APC, o ni ko ni i sohun to n jẹ APC mọ lẹyin ibo gbogbogboo ọdun to n bọ.
Igbakeji aarẹ wa tẹlẹ yii sọrọ ọhun lasiko ti wọn n ṣe ifilọlẹ ikọ awọn ọdọ ti yoo maa polongo ibo fẹgbẹ wọn, eyi ti gomina tuntun to ṣẹṣẹ wọle nipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, jẹ aṣiwaju fun. Adari awọn ọdọ tẹlẹtẹlẹ, Mohammed Maibasira, lo ṣoju fun gomina naa niluu Abuja l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Atiku ṣapejuwe ẹgbẹ APC gẹgẹ bii adamọdi ẹgbẹ ti ọwọ ọlọwọ ati ẹsẹ ẹlẹsẹ sọ di ọkan, toun ko si le pe ni ẹgbẹ oṣelu kan lọ titi, o fi kun un pe ni toun o, PDP nikan ni ẹgbẹ oṣelu to wa lorilẹ-ede Naijiria.
O ni, “Ka sọ tootọ, PDP nikan lẹgbẹ oṣelu nilẹ Naijiria, APC o ki i ṣe ẹgbẹ oṣelu bo ti wu ko mọ, imulẹ laarin ẹgbẹ CPC ati ẹgbẹ Tinubu ni, a si ti ri i bi awọn ẹgbẹ alagbaarijọpọ ti wọn wa nigba kan ṣe poora lojiji. Emi o ro pe a le gbọ nipa APC mọ lẹyin ibo to n bọ yii, a maa fi ibo le wọn wọle lọdun 2023 ni.
Lori ọrọ pe boya mo le ṣe ijọba alagbada daadaa, ijọba awa-ara-wa ta a ni ni Naijiria yii, awa kan la fi gbogbo ẹmi wa ja fun un. Ọpọ lo si fi ẹmi ara wọn lelẹ fun ominira ti a n jẹgbadun ẹ lonii yii”.
Atiku tun fi kun un pe, ẹgbẹ oṣelu awọn lo kọkọ bẹrẹ igbimọ awọn ọdọ, o lawọn gbe igbesẹ naa lati tubọ mu itẹsiwaju ba ijọba alagbada lorilẹ-ede yii latara ẹgbẹ awọn ni.
O waa ke pe awọn ọdọ onikọ ipolongo lati ṣiṣẹ fun aṣeyọri ẹgbẹ wọn nipinlẹ ati ipele ijọba ibilẹ nipa kiko awọn ọdọ jọ, ki wọn si fun wọn nireti lati ṣi ọkan wọn kuro nibi awọn ọrọ ibajẹ tawọn APC ti ko si wọn lori, ati eemọ ti wọn ti foju wọn ri lati bii ọdun meje sẹyin.