Lẹyin oṣu marun-un ti Jimoh atawọn ẹmẹwa rẹ ja ọkada gba l’Akurẹ lọwọ tẹ wọn

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn afurasi ole a-ji-ọkada meji lọwọ palaba wọn ṣegi, awọn agbofinro lo mu wọn lagbegbe Ẹyin-Ala, nijọba ibilẹ Guusu Akurẹ, lọsẹ to kọja yii.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn afurasi mejeeji, Jimọh Dele ati Uwanfor Destiny, lọwọ pada tẹ lẹyin bii oṣu marun-un gbako ti wọn ti ja ọkada ọlọkada gba lọwọ oni nnkan.
Inu oṣu Kin-in-ni, ọdun ta a wa yii, ni wọn ni Jimoh, Destiny ati ẹni kẹta wọn tawọn ọlọpaa ṣi n wa da ọlọkada ọhun lọna loju ọna Ala, wọn fipa gba ọkada Honda rẹ, wọn si gbe e sa lọ lati igba naa.
Ọsẹ to kọja ni ẹnikan to jẹ ẹgbọn ọlọkada ọhun deedee ṣalabaapade awọn gende ọkunrin mẹta ti wọn n ja lori ọkada kan, nigba to si wo ọkada ti wọn n ja le lori naa daadaa, o ṣakiyesi pe o jọ alupupu aburo rẹ tawọn ole ja gba loṣu marun-un sẹyin.
Kia lo lọọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe meji lara awọn afurasi naa.
Awọn ọlọpaa la gbọ pe wọn tun ba ọkada ọlọkada mi-in nile Destiny lasiko ti wọn lọọ wa ile rẹ wo, ko si jẹ kawọn agbofinro ọhun laagun jinna to fi jẹwọ fun wọn pe nibi ti oni nnkan gbe e si labule Gbelegi, loun ti lọọ ji i gbe lọjọ kẹsan-an, osu Kẹfa, ta a wa yii.

Ọkada ọlọkada meji, redio abugbamu kan ati ada lawọn ẹru ofin ti wọn ri gba pada lọwọ awọn afurasi ọhun.

Leave a Reply