Lẹyin oṣu meji ti ọkọ rẹ ku, wọn ṣa Iya Sunday ladaa pa sinu oko obi n’Ikire

Idowu Akinrẹmi, Ikire

Inu Ibanujẹ nla lawọn ẹbi obinrin ẹni ọgọta ọdun ti orukọ rẹ n jẹ Ọmọbọla Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Iya Sunday, lagboole Buoye,  niluu Ikire,  wa bayii, pẹlu bawọn amookunseka ẹda kan ṣe ṣa a pa sinu oko ọkọ rẹ to wa labule Olubadan,  n’Ikire, ipinlẹ Ọṣun.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ, ẹni to jẹ akọbi oloogbe naa, Niyi Adeyẹmọ, ṣalaye pe iṣẹlẹ naa waye lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun yii.

O ni lẹyin ti iya oun kuro ni ṣọọṣi laaarọ Mọnde lo gba oko lọ, oun si sọ pe to ba di aago meji ọsan, oun yoo lọọ fi ọkada gbe e loko wa sile.

O ni si iyalẹnu oun, nigba toun de oko, inu agbara ẹjẹ loun ba iya oun ti wọn ti ṣa a pa sinu oko obi baba oun.

Niyi ni ṣaaju ni ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Afeez Kọlawọle ti fi ada le iya oun kuro ninu oko naa, ko too di pe wọn pada pa a patapata.

O fi kun un pe bẹẹ ni wọn si ko owo to wa ninu apo iya naa lọ lẹyin ti wọn pa a tan.

Bakan naa ni Sunday Adeyẹmọ to jẹ ọmọ keji Oloogbe ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyi to ba a lọkan jẹ gidigidi. Sunday ni ọjọ keji, oṣu kọkọkanla, ọdun 2020, ni baba awọn ku, eyi to ṣẹ̀ṣẹ̀ pe oṣu meji.  Ko too di pe awọn oṣika ẹda tun pa iya oun lọjọ Aje, Mọnde yii.

Alukoro Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Arabinrin Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.  O ni ọwọ ti tẹ afurasi ọdaran kan torukọ rẹ n jẹ Afeez Kọlawọle,  o si ti wa lakolo ọlọpaa n’ Ikire.

Ọpalọla lawọn yoo fi afurasi naa ṣọwọ si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun fun iwadii siwaju si i.

Leave a Reply