Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ilọrin paṣẹ ki lanlọọdu kan, Ọgbẹni Bakinde AbdulWaheed, lọọ ja ilẹkun ile rẹ lẹyin ọdun mẹta ti tẹnanti rẹ, Ọgbẹni Akin Ola, dawati, to si tilẹkun mọ ile lai dagbere.
Onidaajọ Moshood Ajibade lo paṣẹ naa lẹyin ti Ọgbẹni AbdulWaheed to nile mu ẹsun lọ sile-ẹjọ pe lati nnkan bii ọdun mẹta sẹyin ni ayalegbe oun, Ọgbẹni Akin Ọla, ti dawati, o ti ilẹkun ile pa, bẹẹ ko dagbere ibikankan, ati pe gbogbo igbiyanju ni awọn ti ṣe ki wọn le mọ ibi ti Akin Ọla wa, ṣugbọn pabo lo ja si.
Ajibade paṣẹ pe ki wọn lọọ ja ilẹkun ile naa niṣoju awọn oṣiṣẹ ile-ẹjọ, ki wọn si ko gbogbo ẹru inu ẹ jade, ki wọn ko eyi to wulo nibẹ lọ si ọgba ile-ẹjọ titi di akoko ti ofin gba wọn laaye mọ, ṣugbọn ti wọn o ba kofiri Ọgbẹni Akin Ọla, ki wọn ta gbogbo dukia naa, ki lanlọọdu si yọ owo ọdun mẹta rẹ nibẹ, ki wọn ko iyooku pamọ titi di igba ti Akin Ọla ba too yọju, ki wọn si ri i pe wọn ka gbogbo dukia ti wọn ba ninu ile, ki awọn ẹlẹrii si buwọ lu iwe.
Ọgbẹni AbdulWaheed ṣalaye fun ile-ẹjọ pe ṣe ni Ọgbẹni Akin Ọla fẹẹ ran oun lọ sọrun lai tọjọ, tori pe owo ile naa loun fi n gbọ bukata ara oun, ọpọ eeyan si ti n wa pe wọn fẹẹ gba ile ọhun, ṣugbọn ilẹkun to ti pa lo da wahala silẹ.