Lẹyin ọdun mẹtalelogun to ti n jokoo, Yinka Ayefẹlẹ ti le dide kọrin bayii

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Gbajugbaja akọrin Tungba nni, Joel Ọlayinka Ayefẹlẹ, ti n dide duro bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, eyi si jẹ lẹyin ọdun mẹtalelogun to ni ijamba ọkọ to kan eegun ẹyin rẹ.

Ki i ṣe pe Yinka Ayẹfẹlẹ ṣiṣẹ abẹ lo fi le duro lori ẹsẹ rẹ lasiko yii, ọkan ninu awọn ololufẹ rẹ ti wọn n pe ni Ọnarebu Dare Akande, ti inagijẹ ẹ n jẹ Obama l’Amẹrika lo ra kẹkẹ kan to yatọ si ti ijokoo fun Yinka.

Bo tilẹ jẹ pe o le jokoo ninu ẹ to ba wu u, sibẹ, bọtinni kan wa lara kẹkẹ naa to jẹ beeyan ba ti tẹ nnkan ti yoo fi naro bayii, kẹkẹ naa yoo ga soke ni, ẹni to si wa ninu ẹ yoo le duro lai si iṣoro kankan.

Alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii ni Yinka Ayefẹlẹ ṣafihan kẹkẹ aramanda naa, niṣe lo duro ninu ẹ girigiri to si n rẹrin-in ayọ, kedere lo si han pe ẹbun pataki naa dun mọ ọn ninu gidi.

Oju opo Instagiraamu ni Ayefẹlẹ gba lọ, nibi lo ti ṣafihan fidio kan to ti duro ninu kẹkẹ yii, bẹẹ lo n dupẹ lọwọ Darẹ Akande, o loun lo ra kẹkẹ naa foun.

Lẹyin eyi lo tun kọ akọle kan to ka bayii pe

‘’Ara tù mi pupọ bayii kuro ninu inira mi… Ọnarebu Dare Akande lo ra eyi fun mi (kẹkẹ naa). O o ni i mọ inira ni gbogbo ọjọ aye rẹ. O ṣeun pupọ, Dare Akande ti n jẹ Obama l’Amẹrika. Mo le dide kọrin bayii nibikibi. O jẹ ki igbagbọ mi pe ma a ṣi dide rin tun le kun si i. Mo gbagbọ.’’

Bẹẹ ni Yinka Ayefẹlẹ fi ẹmi imoore ati idunnu han si ẹni to ṣe e loore nla yii, to jẹ ko le duro lori ẹsẹ rẹ lẹyin ọdun gbọgbọrọ.

Ọjọ kejila, oṣu kejila, ọdun 1997, ni Yinka Ayefẹlẹ nijamba ọkọ to kan egungun ẹyin rẹ, latigba naa ni ko ti le dide mọ, ti ko si le fẹsẹ rẹ rin. Ṣugbọn ni bayii, Ayefẹlẹ ti n dide naro, o si ti n dide kọrin nibikibi.

 

Leave a Reply