Lẹyin ọjọ kẹrin ti wọn ti n wa Aminat ni wọn ba oku ẹ ninu kanga n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni ajọ panapana, ẹka ti ipinlẹ Kwara, yọ oku ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun kan, Aminat, ninu kanga lagbegbe Oke-Adini, Alagbado, Ilọrin, lẹyin ọjọ kẹrin ti wọn ti n wa a.

ALAROYE gbọ pe lati bii ọjọ mẹrin sẹyin ni awọn mọlẹbi Aminat ti n wa a kiri, ti wọn ko si mọ ibi to gba lọ, ko too di pe wọn ri oku ẹ ninu kanga. Ọgbẹni Abdulfatah to jẹ alamuleti wọn lo pe ajọ panapana si iṣẹlẹ yii, ti awọn oṣiṣẹ ijọba naa si de agbegbe Alagbado lẹyin iṣẹju mẹjọ ti wọn gba ipe pajawiri ọhun.

Ọga ajọ yii, Ọmọọba John Falade, fi ibanujẹ rẹ han lori iṣẹlẹ buruku naa, o gba awọn olugbe ipinlẹ Kwara nimọran lati maa wa ni toju-tiyẹ ti aparo fi n riran nigba gbogbo, ki wọn si maa kiyesi awọn alabaagbe wọn lati dena awọn iṣẹlẹ abami bayii.

Leave a Reply