Lẹyin ọjọ mẹwaa nigbele, akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun bọ lọwọ arun Koronafairọọsi

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Wọle Oyebamiji, ti jajabọ lọwọ arun Koronafairọọsi bayii.

Ọjọ mẹwaa sẹyin ni Kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Ọṣun, Dokita Rafiu Isamọtu, kede pe baba naa ti ni arun yii, o si ti wa nigbele fun itọju.

Lọsan-an oni ni Isamọtu kede pe bo tilẹ jẹ pe eeyan mẹtalelogun larun naa tun ti kọ lu l’Ọṣun, sibẹ, ara Oyebamiji atawọn eeyan mọkanlelogun mi-in ti ya patapata lẹyin ayẹwo ẹlẹẹkeji ti wọn ṣe fun wọn.

 

Leave a Reply