Lẹyin ọsẹ kan to bimọ sọgba ẹwọn, ile-ẹjọ gba beeli Kẹmi ti wọn mu lasiko iwọde SARS l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Lati bii ọsẹ kan sẹyin ni ọkan-o-jọkan awuyewuye ti n waye ni kete ti ọmọbinrin kan, Kẹmisọla Ogunniyi, bimọ sinu ọgba ẹwọn awọn obinrin to wa laduugbo Surulere, niluu Ondo.

Kẹmisọla atawọn obinrin mẹta mi-in, Ayọdele Bukunmi, Ojo Samuel ati Ani Obinna, lawọn sọja mu lọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja, lori ẹsun pe wọn wa lara awọn to lọọ dana sun olu ile ẹgbẹ APC to wa loju ọna Ọba Oyemẹkun, niluu Akurẹ, ti wọn si fa wọn le ọlọpaa lọwọ fun igbesẹ to yẹ.

Ile-ẹjọ Majisireeti to wa l’Oke-Ẹda, ni wọn kọkọ ko wọn lọ, nibi ti adajọ ti pasẹ pe ki wọn ṣi lọọ ko wọn pamọ sọgba ẹwọn lẹyin to ti fi iwe ẹsun wọn ṣọwọ si ajọ to n gba adajọ nimọran.

Awọn eeyan ko fi bẹẹ gbọ ohunkohun mọ nipa ọmọbinrin ẹni ọdun mejidinlogun ọhun atawọn yooku rẹ latigba ti wọn ti n tẹsiwaju lori igbẹjọ wọn nile-ẹjọ giga to wa ni Olokuta, l’Akurẹ, titi di Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ti okiki deedee kan pe o ti bimọ sinu ọgba ẹwọn to wa l’Ondo.

Lati igba naa lagbẹjọro rẹ, Amofin Tọpẹ Yomẹkun, atawọn eeyan kan ti n pariwo, ti wọn si tun n rawọ ẹbẹ si Kọmiṣanna feto idajọ nipinlẹ Ondo, Amofin Charles Titiloye, ati ijọba ki wọn ṣiju aanu wo o nitori ọmọ to bi.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti ariwo naa fẹẹ maa pọ ju bo ṣe yẹ lọ ni kọmisanna feto idajọ sare fi atẹjade kan sita funra rẹ, ninu eyi to ti gba agbẹjọro rẹ niyanju lati pada sile-ẹjọ lori ọrọ beeli onibaara rẹ.

Titiloye ṣeleri pe ijọba ko ni i ta ko gbigba beeli olujẹjọ naa mọ gẹgẹ bi awọn ti n ṣe latẹyinwa.

Adajọ faaye beeli rẹ silẹ pẹlu miliọnu kan naira ati oniduuro kan ni iye owo kan naa.

Nigba to n fi ẹmi imoore rẹ han lori ipinnu onidaajọ ọhun, Amofin Yọmẹkun ni ile-ẹjọ ti pasẹ ki wọn fi ọmọbinrin naa silẹ ki igbesẹ gbigba beeli rẹ too pari.

 

Leave a Reply