Tanka epo gbina l’Ogere, eeyan meji ku, tirela mọkanla ati ọkọ ayọkẹlẹ meji jona raurau

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lẹyin ti tanka epo kan ṣubu ni nnkan bii aago mẹfa idaji kọja ogun iṣẹju lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹfa yii, ajọ FRSC ti fidi ẹ mulẹ pe eeyan meji lo ku, tirela mọkanla ati ọkọ ayọkẹlẹ meji lo si tun jona raurau ninu iṣẹlẹ naa, eyi to waye l’Ogere, loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan.

Adari FRSC nipinlẹ Ogun, Ahmed Umar, ṣalaye pe iwaju ibi kan ti wọn maa n ko tirela rẹpẹtẹ si, eyi ti wọn n pe ni Romina Trailer Park, ni ijamba ina naa ti ṣẹ.

O ni epo ni tirela to ṣubu ọhun gbe, bo si ti fẹgbẹ lelẹ ni ina nla sọ. Ina to sọ lara ẹ naa ni awọn tirela yooku to wa nitosi sọ di orin, ti wọn n kọ ọ, bẹẹ ni ina ọhun si ṣe ran titi to fi jo ọkọ mẹtala gburugburu, teeyan meji si dero ọrun.

Nigba ti ijamba naa n lọ lọwọ, ati lẹyin ọpọlọpọ wakati to ti ṣẹlẹ, niṣe lawọn awakọ to ka mọ oju ọna ọhun ko rọna lọ, sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ to lagbara ni wọn koju, awọn mi-in ti wọn si tete gbọ nipa ẹ ṣẹ ọna gba, wọn ko tẹri si ọna to ti di pa naa rara.

Awọn kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe yatọ sawọn to ku yii, ọpọ eeyan lo tun fara pa, ti wọn ko wọn lọ sọsibitu. Wọn ni ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ lawọn panapana pa ina yii, ṣugbọn niṣe ni ina ọhun tun ṣẹ yọ lẹyin igba naa, nitori ọpọlọpọ epo to ti ṣan kaakiri agbegbe yii.

Ko sohun to jẹ ki ina ọhun ran kia bẹẹ ju ti sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ to ti wa nidaaji kutu naa lọ. Eyi lo jẹ kawọn ọkọ to wa nitosi ma le sa, ti ina ọhun si bẹrẹ si i ran kiri.

Leave a Reply