Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ṣe ni ibẹru bojo gba ọkan awọn eeyan ilu Ajọwa Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, kan pẹlu bawọn Fulani darandaran tun ṣe sa ọkunrin ẹni ogoji ọdun kan, Dayọ Festus pa sinu oko rẹ lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii.
gẹgẹ bi alaye ti ọkan ninu awọn ẹbi oloogbe ọhun, Ọgbẹni Audu Badru, ṣe f’ALAROYE, o ni ó ti to bii osu diẹ sẹyin ti awọn ti n ṣakiyesi bi awọn ajoji Fulani kan ṣe n ya wọ ilu Ajọwa lati Oke-Ọya.
O ni ọpọlọpọ igba ni Dayọ ti lọọ fẹjọ awọn darandaran naa sun ni tesan lori bi wọn ṣe n fi maaluu bá awọn nnkan to fi owo banki to ya gbin sinu oko rẹ jẹ.
Agbegbe ibi tí oko ọkunrin naa wa la gbọ pe ko fi bẹẹ jinna rara si aala ipinlẹ Kogi ati ilu Ajọwa Akoko.
Dayọ nikan ni wọn lo lọọ ṣiṣẹ ninu oko rẹ lọjọ naa niwọn igba to ti jẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ti ọpọ awọn Musulumi ti wọn jọ n da oko lagbegbe ọhun ki i saaba lọ soko.
Kayeefi nla lo jẹ fawọn eeyan ọkunrin ti inagijẹ rẹ n jẹ Sẹfun naa nigba ti wọn deede ba oku rẹ ninu agbara ẹjẹ, nibi ti wọn ṣa a pa si pẹlu ọwọ rẹ mejeeji ti wọn de sẹyin.
Alaga tẹlẹ fun ẹgbẹ awọn ọmọ Ajọwa Akoko nijọba ibilẹ, Alagba Bakare Ajayi, ni lati igba tawọn ajoji Fulani ọhun ti n ya wọ wọ agbegbe awọn ni jinnijinni ti n mu awọn eeyan,
Ọpọlọpọ agbẹ lo ni wọn ti pa oko wọn ti ti wọn ko laya lati lọọ ṣiṣẹ mọ nitori ibẹru akọlu awọn darandaran.
O ni iṣẹlẹ yii wa lara ohun to n ṣokunfa iyan ati ọwọn gogo ounjẹ to n waye niluu Ajọwa ati agbegbe rẹ lọwọlọwọ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ọga ọlọpaa to wa ni Ikarẹ Akoko, Ọgbẹni Rasak Rauf, ni ṣe lawọn onisẹ ibi naa kọkọ fun Dayọ lọrun pa ki wọn too tun ṣa a ladaa ni gbogbo ara.
O ni eto ti n lọ lọwọ lori bi awọn ṣe fẹẹ fọ inu awọn aginju to yí ilu Ajọwa ka kọwọ le tẹ awọn Fulani ọdaran naa laipẹ rara.