Lẹyin ti adajọ sun igbẹjọ si ọjọ Ẹti, Furaidee, wọn ti da Sunday Igboho pada satimọle

Jọke Amọri

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii ni ireti wa pe wọn yoo da ẹjọ ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho.

Ni nnkan bii aago mẹrin kọja ni wọn gbe ajijagbara naa wọ kootu ile-ẹjọ kan ti wọn n pe ni Cour De’appal De Cotonou to wa ni orileede Benin.

Lasiko igbẹjọ naa ni awọn agbẹjọro Oloye Adeyẹmọ ati ti ilẹ Benin ṣe alaye loriṣiiriṣii. ALAROYE gbọ pe ẹsun ti wọn n tori rẹ ba Igboho ṣẹjọ ni i ṣe pẹlu iwe irinna to fi wọ orileede naa, bo tilẹ jẹ pe ko si ẹnikẹni ninu igun mejeeji awọn agbẹjọro yii to ba oniroyin sọrọ lori ohun to ṣẹlẹ nile-ẹjọ.

Ireti wa pe wọn yoo fi ori ẹjọ naa ti sibi kan ni ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii.

ALAROYE gbọ pe ọkan ninu awọn agbẹjọro agba ti wọn fẹẹ lo fun ẹjọ naa lati ṣatilẹyin fun Oloye Sunday Adeyẹmọ, Dokita Maliki Falọla, yoo balẹ si orileede Olominira Benin laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, yii lati orileede France to n gbe..

ALAROYE gbọ pe ki ohun gbogbo le lọ bi wọn ṣe fẹ ni wọn fi gba agbẹjọro agba naa, ẹni ti wọn bi ni orileede Benin, ṣugbọn to jẹ ọmọ Yoruba. Ọkunrin yii la gbọ pe o wa ninu awọn ti wọn kọ iwe ofin ti orileede Benin n lo, o si jẹ gbajugbaja agbẹjọro ni orileede naa.

Ẹni to yọ ọrọ naa sọ fun ALAROYE sọ pe oun ni yoo dari awọn agbẹjọro ti yoo tun pade ni kootu Benin lọjọ Ẹti yii lati ṣatilẹyin fun Igboho.

ALAROYE gbọ pe wọn ti da Igboho pada si atimọle titi ọla ti igbẹjọ naa yoo tun waye.

Leave a Reply