Lẹyin ti awọn ọmọ fasiti Ọyọ lu akẹkọọ ẹgbẹ wọn pa, eyi lohun ti awọn alaṣẹ fasiti naa ṣe

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori ti wọn na akẹkọọ ileewe ọhun kan pa, awọn alaṣẹ ileewe giga Ajayi Crowther University, niluu Ọyọ, ti kede gbogbo ọṣẹ yii gẹgẹ bii asiko ọfọ, ninu eyi ti wọn yoo ti gbaawẹ fun odidi ọjọ mẹta.

Ọga agba fasiti yii, Ọjọgbọn Timothy Abiọdun Adebayọ, lo fidi eyi mulẹ ninu ipade oniroyin ti oun atawọn igbimọ alaṣẹ ileewe naa ṣe ninu ọgba fasiti ọhun lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn (27), oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii.

Nigba ti wọn n sọrọ lori iṣẹlẹ yii ninu ipade ti wọn ṣe pẹlu awọn oniroyin lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde yii, awọn alaṣẹ ileewe ọhun fidi ẹ mulẹ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iya àtọwọ́dá ti wọn fi sọ ọkunrin alaaye naa doloogbe pata lawọn ti le danu kuro nileewe naa.

Ṣugbọn wọn ta ko abala to ni i ṣe pẹlu ọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ninu iroyin to n ja ran-in kiri, ọhun. Wọn ni “Lodi si iroyin to n ja ran-in ran-in kiri nipa ọrọ o-ṣẹgbẹ-okunkun, ko ṣẹgbẹ-okunkun, a layọ lati fidi ẹ mulẹ, a ṣi n fi gbogbo ẹnu sọ ọ pẹlu idaniloju pe ko ṣọmọ ẹgbẹ okunkun laarin awọn akẹkọọ wa, nitori ileewe yii ko faaye silẹ fun ẹgbẹ okunkun ati ohunkohun to lodi sofin tabi to lewu fun awujọ wa.

Gẹgẹ bi Ọjọgbọn Adebayọ ti i ṣe ọga agba Fasiti ACU ṣe ṣalaye, “Ni nnkan bii aago mẹjọ aabo aarọ ọjọ Ṣatide lolori awọn ẹṣọ alaabo ileewe yii pe mi pe oun ri oku kan nilẹ. Mo ro pe ẹni yẹn ko ti i ku, mo ni ko lọọ gbe e ka le toju ẹ nileewosan aladaani nigboro ilu Ọyọ, nitori iru ẹ ki i ṣe nnkan ta a le tọju nileewosan wa nibi. Ṣugbọn ọ ṣe ni laaanu pe ọmọ yẹn ti ku.

‘‘Gẹgẹ bii olori igbimọ alaṣẹ ileewe yii, a ṣewadii, a si gbọ pe iya ni wọn fi jẹ ẹ to fi ku. A si ṣa awọn ogun (20) ta a fura si pe wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ yẹn, a fa wọn le awọn ọlọpaa lọwọ.

Olori ẹgbẹ awọn akẹkọọ ileewe yii ran wa lọwọ pupọ lori ọrọ yii. Wọn ba wa wa fidio ti wọn ya nibi ti wọn ti n na ọmọ yẹn lọwọ. Iyẹn la fun awọn ọlọpaa ti wọn fi ṣewadii tiwọn.

Lẹyin iwadii awọn ọlọpaa ni wọn da mẹjọ pada ninu awọn ọmọ yẹn, wọn ni awọn yẹn ko lọwọ ninu iwa ọdaran yẹn. Awọn mejila yooku wa lọdọ awọn ọlọpaa ni Iyaganku, n’Ibadan, bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii”.

Nigba to n sọrọ lori igbesẹ ti awọn alaṣẹ ileewe yii gbe lori iṣẹlẹ ọhun, ati bi wọn yoo ṣe dena iru ẹ lọjọ iwaju, Ọjọgbọn Adebayọ, ṣalaye pe, “Lọjọ keji iṣẹlẹ yii ti i ṣe Sannde ana, lawa igbimọ alaṣẹ ileewe yii gbera lọ siluu Abuja lati tufọ ohun to sẹlẹ fun awọn obi ọmọ yẹn. Ọsan yii (Mọnde), paapaa la ṣẹṣẹ ti Abuja de.

“Mo ti ba gbogbo awọn akẹkọọ wa sọrọ lonii. Loorekoore naa la maa n ba wọn sọrọ tẹlẹ. Koda, mo maa n fun wọn ni nọmba foonu mi lati pe mi nigbakuugba ti wọn ba ri ohunkohun to ba ru wọn loju.

“Pipe ti akẹkọọ mi-in ba maa pe mi gan-an, omi-in le sọ pe oun ko lowo lọwọ, ma a si fi bii ẹgbẹrun meji Naira ranṣẹ si i. Bi awọn ọga yooku naa ṣe maa n ṣe ree nitori bii ọmọ la ṣe mu awọn akẹkọọ wa nibi.

“A ti ṣafikun awọn oṣiṣẹ eleto aabo wa lati maa mojuto iṣesi awọn akẹkọọ wa loorekoore. A maa ṣepade pẹlu awọn to lọmọ nileewe yii laarin ọsẹ yii.

“Inu ọfọ la wa bayii, a si maa ṣe e wọ ọjọ Sannde ọsẹ to n bọ ni. Laarin asiko yii la maa gbaawẹ ọlọjọ mẹta, eyi to maa waye laarin Wẹsidee (ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii, si ọjọ Ẹti, Furaidee  (ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu yii”.

Gẹgẹ bii iwadii akọroyin wa, ẹni ọdun mejilelogun (22) ni Alex ti wọn pa yii, ilu Abuja lawọn ẹbi ẹ n gbe, akẹkọọ ọlọdun keji si ni i ṣe lẹka ẹkọ nipa imọ ẹrọ ninu ọgba fasiti naa.

Lalẹ ọjọ Ẹti,  Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn (26), oṣu Karun-un, ọdun yii, lawọn ọmọ ileewe ọhun lu akẹkọọ ẹgbẹ wọn to n jẹ Akor Alex yii pa nitori ti wọn ka foonu ọkan ninu wọn mọ ọn lọwọ.

Pẹlu bo ṣe jẹ pe laarin awọn akẹkọọ to fi inu ọgba fasiti naa ṣebugbe niṣẹlẹ ọhun ti waye, nilegbee awọn akẹkọọ ti wọn n pe ni Shepherd Inn, ninu ọgba fasiti naa, ati paapaa nitori ọwọ alẹ to bọ si, aaye gba awọn akẹkọọ wọnyi bọ sódì lati fiya jẹ ọkunrin ẹni ọdun mejilelogun (22) naa kọja aala. Nnkan bii wakati mẹjọ gbako ni wọn fi da sẹria fun un.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, lẹyin ti wọn ti kọkọ fi lilu da sẹria fun un, ni wọn fi tulaasi fa gbogbo irun ori ẹ kodoro, ki wọn too tun bẹrẹ si i lu u pẹlu igi atawọn nnkan mi-in ti ọwọ wọn ba to.

Lati bii aago mẹwaa alẹ ti wọn ti mu un, wọn ko sinmi lilu ti wọn n lu u titi di aago mẹfa idaji.

Bo tilẹ jẹ pe awọn alaṣẹ fasiti yii pada gbe e lọ sileewosan fun itọju lati gbẹmi ẹ la, wọn ko ti i gbe e kuro nibi ti wọn ti ba a to ti dero ọrun alakeji.

Ọkan ninu awọn akẹkọọ fasiti yii ta a forukọ bo laṣiiri ṣalaye f’ALAROYE pe, “Lẹyin ti wọn lu Alex nilukulu, o ṣubu lulẹ, ko le dide mọ, wọn waa ro pe o kan daku lasan ni, n ni wọn wọ ọ ju sẹgbẹẹ titi nita, pe o maa ji pada nigba ti atẹgun ba fẹ si i, lai mọ pe ọmọkunrin naa ti ku”.

 

Leave a Reply