Awọn agbebọn ti tun ji tiṣa kan gbe n’Ijẹbu o 

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Ṣe ẹ ranti Gbọlahan Ajibọla? Ọmọ ọdun mẹtala to fẹẹ ṣi geeti funya rẹ lalè ọjọ Satide to kọja yii ti awọn ajinigbe mẹfa fi gbe e lọ l’Ọbada-Oko, wọn ti tu u silẹ, o si ti wa pẹlu awọn ẹbi rẹ pada bayii. Ṣugbọn b’oun ṣe n gba itusilẹ ni aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu kẹrin yii, lawọn agbebọn tun ki tiṣa obinrin kan mọlẹ n’Ijẹbu-Oru, laaarọ ọjọ Iṣẹẹgun yii kan naa, lawọn agbebọn ba tun gbe e lọ raurau.

Theresa Ọkẹowo lorukọ tiṣa ti wọn ji yii n jẹ, abilekọ ni. Ileewe Girama Oritamẹrin, n’Ijẹbu- Oru, lo ti n kọ wọn lẹkọọ nipa itọju ati mimojuto ile (Home management) Afi bi wọn ṣe gbe oun naa lọ, ẹnikẹni ko si le sọ ibi to wa bayii.

Ni ti Gbọlahan, aadọta miliọnu(50m) lawọn to ji i gbe n beere fun lọwọ awọn ẹbi ẹ ki wọn too tu u silẹ, boya wọn waa sanwo ọhun tabi bẹẹ kọ ki wọn too fi ọmọ naa silẹ, Oyeyẹmi loun ko mọ nipa iyẹn.

Lẹyin ti wọn tu Gbọlahan ti wọn ji gbe l’Ọbada-Oko silẹ ni wọn tun ji tiṣa gbe n’Ijẹbu-Oru

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Ṣe ẹ ranti Gbọlahan Ajibọla? Ọmọ ọdun mẹtala to fẹẹ ṣi geeti funya rẹ lalè ọjọ Satide to kọja yii ti awọn ajinigbe mẹfa fi gbe e lọ l’Ọbada-Oko, wọn ti tu u silẹ, o si ti wa pẹlu awọn ẹbi rẹ pada bayii. Ṣugbọn b’oun ṣe n gba itusilẹ ni aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu kẹrin yii, lawọn agbebọn tun ki tiṣa obinrin kan mọlẹ n’Ijẹbu-Oru, laaarọ ọjọ Iṣẹẹgun yii kan naa, lawọn agbebọn ba tun gbe e lọ raurau.

Theresa Ọkẹowo lorukọ tiṣa ti wọn ji yii n jẹ, abilekọ ni. Ileewe Girama Oritamẹrin, n’Ijẹbu- Oru, lo ti n kọ wọn lẹkọọ nipa itọju ati mimojuto ile (Home management) Afi bi wọn ṣe gbe oun naa lọ, ẹnikẹni ko si le sọ ibi to wa bayii.

Ni ti Gbọlahan, aadọta miliọnu(50m) lawọn to ji i gbe n beere fun lọwọ awọn ẹbi ẹ ki wọn too tu u silẹ, boya wọn waa sanwo ọhun tabi bẹẹ kọ ki wọn too fi ọmọ naa silẹ, Oyeyẹmi loun ko mọ nipa iyẹn.

Ijinigbe to di iṣẹlẹ ojoojumọ nipinlẹ Ogun yii n ko awọn eeyan lọkan soke, ṣugbọn pẹlu titẹle ilana iṣọra-ẹni gbogbo, ati mimu aabo ara ẹni ni koko lai duro de awọn agbofinro gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe wi, alaafia yoo jọba. Awọn to n ji eeyan gbe kiri yii yoo si wọ gau lọjọ kan lawọn ọlọpaa wi.
Ẹ oo ranti pe Dokita Ọladunni ati Nọọsi Bamgboṣe ti wọn n ṣiṣẹ lọsibitu Jẹnẹra Imẹkọ, naa ṣẹṣẹ ti ọdọ awọn ajinigbe de ni lọjọ Aje, Mọnde, ìyẹn lẹ́yìn ọjọ karun-un ti wọn ti wa nibuba awọn ajinigbe.

Leave a Reply