Lẹyin to ti lo ọdun mẹta lẹwọn, kootu tu Malachy silẹ, wọn ni ko jẹbi

 Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ẹsun idigunjale ni awọn kan ka si ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Tomas Malachy lẹsẹ niluu Iworoko-Ekiti, lọdun 2018, latigba naa lo si ti wa lẹwọn, ki kootu too gbọ ẹjọ rẹ tan lọsẹ to kọja yii, ti wọn si da a silẹ pe ko jẹbi.

Ile-ẹjọ giga kan l’Ado-Ekiti lo da Tomas, ẹni ogoji ọdun silẹ, nigba ti Adajọ John Adeyẹye sọ pe awọn to pe e lẹjọ pẹlu ọlọpaa to ṣoju ko ri ẹri gidi fi gbe ẹsun ole jija naa lẹsẹ lasiko igbẹjọ. Titi di ọjọ ti idajọ si waye yii, ọrọ wọn ko ṣee tẹle, nitori ko kunna to.

Oṣiṣẹ ileeṣẹ mọnamọna ni Malachy Tomas, ohun to gbe e de kootu ko too dero ẹwọn ni pe wọn ni lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2018, wọn lo dihamọra pẹlu ibọn ilewọ ibilẹ kan, o si lọọ ja ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Kọlawọle Damilọla  lole ninu ile rẹ ni Iworoko-Ekiti, nijọba ibilẹ Ifẹlodun/Irẹpọdun.  

Lara awọn ẹru ti wọn gba lọwọ Malachy nigba naa ni foonu, kọmputa alagbeletan ati ẹgbẹrun lọna aadọta naira.

Nigba ti Adajọ Adeyẹye wo ṣaakun ẹsun ti olujẹjọ tori ẹ wa latimọle lati 2018, ti ko si si ẹri gidi to le mu ko gba pe ọkunrin naa jẹbi lo da a silẹ, o ni ko maa lọ sile rẹ lalaafia ara.

Leave a Reply