Ọlagunju kun baba rẹ bii ewure, lo ba lọọ ta ẹya ara rẹ fun babalawo ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti mu ọmọkunrin kan, Ọlagunju, lagbegbe Kajọla, ni Odo-Ọwa, nijọba ibilẹ Oke-Ẹrọ, nipinlẹ Kwara, fẹsun pe o pa baba rẹ, o tun ta awọn ẹya ara rẹ fun awọn oloogun owo.

ALAROYE gbọ pe Ọlagunju ṣeku pa baba rẹ ninu oko rẹ to wa ni agbegbe Kajọla ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, to si lẹdi apo pọ pẹlu awọn to n fi ni ṣowo, o ge ẹya ara baba rẹ lekiri, o ge ọwọ mejeeji lọtọ, o ge ori lọtọ, o si ta a fun baba oniṣegun ọhun. Awọn mọlẹbi lo mu ẹsun lọ sọdọ ọlọpaa pe ọwọ ọmọdekunrin naa ko mọ si iku to pa baba awọn. Ọlagunju naa pada jẹwọ pe ootọ loun lẹdi apo pọ mọ baba oniṣegun lati ṣeku pa baba awọn.

Alukoro ọlọpaa, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni loootọ ni ọmọ agbẹ kan pa baba rẹ, to si ge ẹran rẹ wẹlẹwẹlẹ, to si lọọ ta a fun awọn afiniṣowo lagbegbe Kajọla, Odo-Ọwa, nijọba ibilẹ Oke-Ẹrọ, nipinlẹ Kwara, ti ọwọ sinkun ọlọpaa si tẹ ẹ. Kọmiṣanna ọlọpaa, Mohammed Bagega, ti ni ki wọn ṣe ọrinkinniwin iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply