L’Ọṣun, Tunbọsun fowo olowo ta tẹtẹ, lo ba foju bale-ẹjọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọmọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Ọlatunbọsun Ṣowumi, ti sọ nile-ẹjọ Majisreeti ilu Oṣogbo pe ki i ṣe pe oun na ẹgbẹrun lọna ọrinlelọọọdunrun o din mẹwaa Naira (#370,000) ti oun gba lọwọ obinrin oniṣowo kan, ṣe loun fi ta tẹtẹ.
Ṣowumi lo fara han ni kootu lori ẹsun meji ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu jibiti lilu ati ole-jija eleyii to lodi si ipin okoolenirinwo o din ẹyọ kan ati irinwo o din mẹwaa abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun.
Agbefọba, Adepọju Kayọde, ṣalaye pe ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un ọdun 2022, ni olujẹjọ gba owo naa lọwọ Akinbọrọ Sẹminat, pẹlu ileri pe oun yoo ba a ra apo raisi mẹrindinlogun, ṣugbọn ti ko ṣe bẹẹ.
Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ pe ṣe o jẹbi tabi ko jẹbi, o ni oun ko jẹbi awọn ẹsun naa, bẹẹ ni agbẹjọro rẹ, Kẹhinde Adepọju, rọ kootu lati fun un ni beeli lọna irọrun.
Lẹyin naa ni adajọ Majisreeti naa, Dokita Oluṣẹgun Ayilara, beere lọwọ olujẹjọ pe nibo lo ko owo naa pamọ si, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun gbogbo awọn ti wọn wa ni kootu nigba to sọ pe ṣe loun fi owo naa ta tẹtẹ.
Ṣowumi ni oun ro o pe ki oun sare jere diẹ lori owo naa, ki oun too ba olupẹjọ ra irẹsi rẹ ranṣẹ ni, ti oun fi lọọ fi owo naa ta tẹtẹ, ṣugbọn ti nnkan yiwọ mọ oun lọwọ.
Ninu idajọ Ayilara, o fun olujẹjọ ni beeli pẹlu egbẹrun lọna igba Naira pẹlu oniduuro meji, ti ọkan ninu wọn gbọdọ nile gbigbe lagbegbe kootu, ko si tun jẹ oṣiṣẹ ijọba.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keje, ọdun yii.

Leave a Reply