Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn marun-un lo ku lọwọ aarọ, l’Ọjọruu ti i ṣe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2021 yii, wọn jona ku ni loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan. Nigba ti yoo fi di ọsan ọjọ yii kan naa, awọn mẹta mi-in tun doloogbe ninu ijamba ọkọ mi-in to waye loju ọna yii kan naa, wọn jẹ mẹjọ to doloogbe lọjọ kan ṣoṣo!
Aago mẹta ọsan ku iṣẹju mẹjọ ni ijamba ọkọ keji yii waye, agbegbe Sandcrete, l’Ogunmakin, nibi tawọn meje ti jona ku lọjọ Satide naa ni eyi tun ti ṣẹlẹ.
Kọmamdanti Ahmed Umar ti i ṣe ọga FRSC nipinlẹ Ogun, sọ pe ọkọ bọọsi kan ti nọmba ẹ jẹ SKN 135 XA to n bọ lati Ibadan ni ọwọ rẹ ju, o kuro loju ọna rẹ, o bọ sapa keji ọna, o si lọọ fori sọ jiipu to n bọ lati Eko, eyi ti nọmba rẹ jẹ 02-345 DCT.
Eeyan mejidinlogun ni ijamba naa kan gẹgẹ bi Umar ṣe wi, ọkunrin mẹwaa ati obinrin mẹjọ. Ọkunrin meje ati obinrin mẹjọ lo ni wọn fara pa, nigba ti eeyan mẹta ku. Ninu awọn to ku yii, ẹni kan jona kọja idanimọ ninu wọn gẹgẹ bi Umar ṣe sọ.
Nipa ọkọ to gbina to fi di pe ẹni kan jona ku yii, Ọga FRSC yii sọ pe ọkọ bọọsi to fi oju opo rẹ silẹ to lọọ lari mọ jiipu lo gbina. O ni jiipu run jegejege ni tiẹ ni, koda, awọn ko ti i ri i gbe jade ninu igbo to wọ lọ.
Mọṣuari ọsibitu Idẹra to wa ni Ṣagamu, ni wọn ko awọn oku si, nigba ti wọn ko awọn to ṣeṣe lọ sileewosan kan naa fun itọju.