Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun nigba kan ri, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti sọ gbangba pe ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun ti pin si meji, ati pe igun awọn ‘‘The Osun Progressives’’ loun wa.
Lasiko ti wọn n ṣi ibudo ẹrọ ayelujara kan ti wọn pe ni Digital Nigeria Center (DNC), eyi ti ijọba apapọ kọ sinu ọgba ileewe Muslim Grammar School, niluu Ileṣa, lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee opin ọsẹ yii, ni Arẹgbẹṣọla sọrọ naa.
TOP ni awọn ọmọlẹyin Arẹgbẹṣọla ti wọn wa ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun n pe ara wọn, nigba ti awọn ọmọlẹyin Gomina Oyetọla n pe ara wọn ni IleriOluwa.
Nigba ti Arẹgbẹṣọla n sọrọ nibi eto naa, o ni “Awọn agbalagba sọ pe aiteyin-in-ka la n dọwọ bo o, ẹni ti ko ba mọ, APC ti pin si meji l‘Ọṣun, alaga ẹgbẹ oṣelu APC ti Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ni Ọgbẹni Abdulrasaq Ṣalinṣile, onikaluku n ṣe tiẹ ni, nigba to ba ya, a maa tun un to.
“Alaga ijọ to bi APC tiwa yii, iyẹn The Osun Progressives lo n jẹ Alagba Lọwọ Adebiyi.
“Awọn ti wọn sọ pe awọn ko mọ boya mo wa nibẹ tabi n ko si nibẹ, ki wọn ṣi eti wọn nisinsinyi ki wọn gbọ, TOP ni mi tọkantọkan”
Arẹgbẹṣọla fi kun ọrọ rẹ pe ko si wahala kankan nipinlẹ Ọṣun fun odidi ọdun mẹjọ ti oun fi ṣe gomina, ko si si idi ti oun fi gbọdọ sọ pe ki ipinlẹ naa daru.
Ṣugbọn o ke si Kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun, Ọlawale Ọlọkọde, lati ma ṣe gbe si ẹnikankan lẹyin ninu wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ APC Ọṣun.
Gẹgẹ bo ṣe wi, “Inu mi dun pe ẹ wa (Ọlọkọde), irọ ti pọ ju, awa la ṣakoso ilu yii fodidi ọdun mẹjọ, nigba ti a si wa nibẹ, ẹ lọọ wo akọsilẹ wa, ko si idaamu kankan, ara la fi ṣe o, fodidi ọdun mẹjọ, ko si ọjọ ti mo sun ju wakati mẹta si mẹrin lọ.
“Ki i ṣe wi pe a fi ọkan ṣe e, gbogbo ara la fi ṣe e, ko si idaamu kankan nibi. A ko le sọ pe tori pe a jẹ nnkan kan nibi kan, ki ibi yii daru, mama mi, ọmọ ibi ni, baba mi, ọmọ ibi ni, baba baba baba mi, ọmọ ibi ni, ki la fẹẹ sọ pe ko daru fun?
Ti ẹ ba le tẹle ofin iṣẹ yin, ti ẹ ko fi si ọtun tabi fi si osi, ẹ maa ri i ṣe o.”