Dada Ajikanje
O jọ pe Aarẹ orilẹ-ede Amẹrika, Donald Trump, to ti kọkọ fariga pe oun ko gba abajade esi idibo ti wọn di kọja, nibi ti Joe Biden ti fẹyin rẹ janlẹ, ti n pa ero ẹ da bayii pẹlu bo ṣe sọ pe ọkunrin naa jawe olubori, ṣugbọn eru nla lo ṣe.
Ninu ọrọ kan ti Aarẹ naa kọ sori ikanni abẹyẹfo (Twitter) ẹ lo ti sọrọ ọhun lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii. O ni loootọ lawọn kan le maa sọ pe oun lo wọle, ṣugbọn irufẹ awọn eeyan to n sọ ọ yii, awọn ayederu oniroyin ni, bẹẹ loun gba loootọ pe o wọle ibo, ṣugbọn ojooro ni.
Bo tilẹ jẹ pe Aarẹ orilẹ-ede Amẹrika to n japa mọnu lori bi wọn ṣe kede pe Biden lo wọle ko ti i ri ibi kan pato tọka si pe wọn ja apoti ibo gba nibẹ, tabi ko darukọ adugbo tabi ipinlẹ kan ti wọn ti ṣe madaru to foju han kedere, sibẹ, ariwo ojooro naa lo ṣi n pa kiri.
Bakan naa lo sọ pe ibo to gbe Biden wọle yii, ko si awọn alamoojuto to le sọ pato bo ṣe lọ gan-an. Bẹẹ lo leri pe o di dandan ki oun fi idajọ ile-ẹjo giga nilẹ Amẹrika sọ ohun to n dun ninu Joe Biden yẹn di ibanujẹ mọ ọn lọwọ.
Laipẹ yii lawọn ololufẹ ẹ kan kora wọn jade ni Washington DC, lati ṣewọde ta ko bi iroyin ṣe kede ẹ pe Joe Biden lo wọle, ṣugbọn bi awọn eeyan yii ṣe n wọde kiri, bẹẹ lawọn mi-in naa jade lati ta ko ohun ti wọn n ṣe ti ọrọ si di ranto.
Ogun eeyan lawọn ọlọpaa ti ko, ti awọn mi-in si ṣeṣe pẹlu. Wọn ni nibi ti wọn ti n ṣewọde ọhun gan-an ni Trump gba kọja nigba to fẹẹ lọọ ṣere idaraya gọofu, ẹrin ni wọn lo n rin si wọn, bẹẹ lo tun juwọ pẹlu, ti awọn eeyan naa si n sa a pe, oun ni Aarẹ to dara ju fun ilẹ Amẹrika.
Ju gbogbo ẹ lọ, Aarẹ Trump ti sọ pe, ile-ẹjọ giga ni yoo yanju ọrọ to wa nilẹ yii, nitori ti wọn ba sọ pe Biden wọle ibo Aarẹ, loootọ lo le wọle, ṣugbọn eru lo ṣe, oun yoo si fi ofin wa ojuutu si i.