Ko si ọba alaye to gbọdọ fun ajoji kankan laaye lati tẹdo si agbegbe wọn l’Ondo-Akeredolu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina Rotimi Akeredolu ti ni ko si ọba alaye ipinlẹ Ondo to gbọdọ fun ajoji kankan laaye lati tẹdo si agbegbe wọn lai kọkọ fi to ijọba leti.

Arakunrin ṣe ikilọ yii ninu ọrọ to bawọn eeyan ipinlẹ Ondo lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Gomina ni ojuṣe awọn ọba ni lati kapa iwa janduku awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lagbegbe ti wọn n dari nitori pe ijọba ti ṣetan lati maa kede konilegbele oni wakati mẹrinlelogun níbikíbi ti rogbodiyan ba ti n ṣẹlẹ, bẹẹ ni adari ilu ti iru nnkan bẹẹ ba n ṣẹlẹ lagbegbe rẹ ko ni i sai jiya to tọ labẹ ijọba.

Bakan naa lo tun kilọ fawọn ori ade ọhun pe ijiya to lagbara tí wa nilẹ fun ẹnikẹni ninu wọn to ba ti ṣaigbọran, to si gba alejo tira lai fun ijọba gbọ ko too gbe iru igbesẹ bẹẹ.

Ni ipari ọrọ rẹ, gomina ni oun rọ ẹnikẹni to ba ni awọn nnkan ija oloro lọwọ lati tete waa ko o fun ijọba nitori pe ẹni tọwọ ba tẹ lẹyin ikilọ naa ko ni i sai da ara rẹ lẹbi.

O ni obi kọọkan gbọdọ gbiyanju ati mojuto awọn ọmọ wọn, ki wọn si maa kílọ fun wọn lori biba wọn mu oogun oloro nitori pe ijọba ti da awọn agbofinro sita lati maa fi panpẹ ofin gbe ẹni ti wọn ba ti fura si pe o mu oogun oloro.

 

Leave a Reply