Lori ẹsun ifipabanilopọ: ijọba Eko n ṣeto ẹwọn gbere fun Baba Ijẹṣa

Faith Adebọla, Eko 

Bo ba jẹ ti awọn ẹsun tijọba Eko ka si Baba Ijẹṣa lẹsẹ nile-ẹjọ maa fi ṣe ni, ẹwọn gbere ni idajọ ti gbajugbaja alawada oṣere tiata naa yoo fi jura laipẹ.

Ninu atẹjade kan lati ọfiisi onidaajọ agba ati kọmiṣanna feto idajọ nipinlẹ Eko, Amofin agba Moyọsọrẹ Onigbanjo, sọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, pe lẹyin iwadii tawọn ṣe lori iṣẹlẹ ọhun, ọna marun-un lọkunrin naa ti lufin iwa ọdaran nipinlẹ Eko, ẹsun marun-un ọtọọtọ naa si lawọn maa ba a ṣẹjọ le lori.

Akọkọ ni ẹsun biba ọmọde laṣepọ ti ijiya rẹ jẹ ẹwọn gbere.

Ekeji ni fifipa ko ibasun fun ọmọde ti ijiya rẹ jẹ ẹwọn gbere bakan naa.

Ẹkẹta ni igbiyanju lati ba ọmọde lo pọ ti ijiya rẹ jẹ ẹwọn ọdun mẹrinla.

Ẹkẹrin ni keeyan maa fọwọ pa ọmọde lara lọna aitọ ti ijiya rẹ jẹ ọdun meje

Ẹkarun-un ni fifipa ru ọkan ọmọde soke fun ibalopọ  ti ijiya rẹ ko ju ọdun mẹta lọ.

O kadii atẹjade naa pe: “Bo tilẹ jẹ pe ijọba maa ri i daju pe wọn ko tẹ ẹtọ Baba Ijẹṣa mọlẹ labẹ ofin lori ọrọ yii, sibẹ a ko ni i kaaarẹ lati ri i pe ẹnikẹni to ba jẹbi ṣiṣe ọmọde baṣubaṣu ko mu un jẹ, onitọhun gbọdọ fimu kata ofin lai fakoko ṣofo ni.

“A fi da ẹyin olugbe Eko ati gbogbo ọmọ Naijiria loju pe, nibaamu pẹlu imọran ta a ri gba, a maa wọ Baba Ijẹṣa tuurutu dele-ẹjọ laipẹ, pẹlu awọn ẹsun ta a sọ loke yii.”

Tẹ o ba gbagbe, lati ọjọ kejilelogun, oṣu kẹrin, to kọja yii, ni wọn ti fẹsun kan Baba Ijẹṣa, tawọn ọlọpaa si ti fi pampẹ ofin mu un sahaamọ wọn, wọn lo fipa ba ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹrinla kan laṣepọ.

Wọn tun fẹsun kan ọkunrin naa pe latigba tọmọbinrin ọhun ti wa lọmọ ọdun meje lo ti fipa ṣe kinni fun un nile oṣere tiata ẹgbẹ ẹ kan, Damilọla Adekọya, tawọn eeyan mọ si Princess.

Ọrọ naa di awuyewuye gidi lori atẹ ayelujara, o si fa ọpọ aawọ laarin awọn oṣere tiata ẹgbẹ rẹ, latari bawọn kan ṣe faake kọri pe wọn ko gbọdọ gba beeli afurasi ọdaran ọhun, tawọn mi-in si n sọ pe awọn kan lo diidi kẹ pampẹ fun Baba Ijẹṣa lati mu un, ati pe ọrọ naa ko buru to bi wọn ṣe n gbe e kiri.

Ẹyin eyi ni fọran fidio to ṣafihan ohun to ṣẹlẹ lọjọ iṣẹlẹ naa bọ sori ayelujara, eyi si tun da awuyewuye mi-in silẹ lọtọ.

 

Leave a Reply