Amọtẹkun Ondo tun da awọn Fulani mẹtadinlogoji pada siluu wọn

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Isọri awọn Fulani mi-in ni ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo tun ti da pada si ipinlẹ wọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lori ẹsun gbigba ọna ẹburu wọle.

Awọn Fulani ọhun ti wọn to bii mẹtadinlogoji (37) ni wọn ka mọ inu igbo ọba to wa lagbegbe Ẹlẹgbẹka, loju ọna marosẹ Ifọn si Ọwọ, nijọba ibilẹ Ọsẹ.

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin bii ọjọ mẹta ti awọn Amọtẹkun da awọn Fulani mejilelogoji ti wọn ko niluu Okitipupa pada si ipinlẹ Jigawa ati Kano ti wọn ti wa.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alakooso ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọndo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ni kete tawọn eeyan agbegbe naa ti kofiri ọgọọrọ awọn Fulani ọhun ni wọn ti pe awọn lori ago.

Nigba ti wọn si béèrè ibi tí wọn ti n bọ, o ni ọpọ ninu wọn ni Oke-Ọya lawọn ti wa, nigba tawọn mi-in jẹwọ pe ipinlẹ Ogun lawọn wa tẹlẹ.

O ni igba ti wọn ko ri alaye to nitumọ ṣe lori idi ti wọn fi fẹẹ waa tẹdọ si ipinlẹ Ondo lawọn ko wọn sinu ọkọ ti yoo gbe wọn pada siluu koowa wọn.

Leave a Reply