Lori ọna Ibadan/Iwo/Oṣogbo, awọn ori-ade rawọ ẹbẹ si Oyetọla ati Makinde

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn lọbalọba ni ẹkun Iwọ-Oorun Ọṣun ti ke si gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla ati gomina ipinlẹ Ọyọ, Enjinnia Ṣeyi Makinde lati ṣatunṣe oju-ọna to wa lati Ibadan si Iwo kọja si Oṣogbo.

Ninu iwe akọsilẹ kan ti awọn ọba mẹẹdogun lati agbegbe naa fọwọ si, ti Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ka fawọn oniroyin ni wọn ti ṣalaye pe oju ọna naa ti di panpẹ iku, yoo si nilo idasi awọn gomina naa kiakia.

 

Wọn ṣalaye pe ijọba ibilẹ mẹwaa ni oju-ọna yii ni ipa lori wọn ni iha Iwọ-Oorun Ọṣun, lara wọn si ni ijọba ibilẹ Ayedire, Ọlaoluwa, Ẹgbẹdọrẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, bẹẹ naa lo si ri nipinlẹ Ọyọ

“Gomina wa daadaa, Gboyega Oyetọla, idi pataki ọrọ yii ni lati fi ori-ade parọwa si ọ lati ma ṣe dawọ duro ninu iṣẹ takuntakun ti o bẹrẹ lọdun kan sẹyin, ki ẹ jọwọ, ba wa ṣatunṣe oju-ọna Oṣogbo si Iwo titi de aala ipinlẹ Ọyọ.

 

“O wa ninu iwe iroyin pe kọmiṣanna fun eto iroyin nipinlẹ Ọṣun, Rẹmi Ọmọwaye, sọ nigba naa pe atunṣẹ oju-ọna yii yoo mu ki gbigbe ere-oko lati ibi kan sibomi-in rọrun pupọ lagbegbe naa.

“Ọmọwaiye ṣeleri pe ipinlẹ Ọyọ yoo ṣatunṣe kilomita ọgbọn o din diẹ (29.2km), nigba ti Ọṣun yoo ṣe kilomita to le diẹ ni marunlelaaadọta (55.4km) ti yoo bẹrẹ lati Dele Yes sir, titi de aala ipinlẹ Ọyọ.

 

“Oju-ọna yii ti buru pupọ, koto ti pọ ju, bẹẹ ni agbara ojo ti wọ abala kan lọ tan, ko si mọto to le lọ geerege nibẹ, ọpọlọpọ ọkọ lo ti bajẹ, ti awọn dẹrẹba si ti pa wọn ti nitori ojoojumọ ni wọn n nawo le ọkọ wọn lori.

 

“Bi ọna yii ṣe wa ti mu ifasẹyin ba eto ọrọ-aje latari bi awọn onimọto ko ṣe raaye koja mọ. Inu oṣu Kẹfa, ọdun yii, aini awọn ijọba ipinlẹ mejeeji ṣeleri pe awọn ti gbe iṣẹ atunṣe oju-ọna naa fun kọngila, ṣugbọn a ko gburoo wn.

 

“Kọmianna Ọṣun, Rẹmi Ọmọwaye, ati ti Ọyọ, Khinde Ṣangodoyin sọ nigba naa pe inu oṣu Keje, ni iṣẹ naa yoo bẹrẹ”.

Awọn ori-ade naa gboṣuba funjọba ipinlẹ mejeeji fun ifọwọsowọpọ wọn lori awọn iṣẹ idagbasoke, lai fi ti ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ ti wọn wa ṣe, eleyii ti wọn ni o n mu ki alaafia maa jọba ninu ilu.

Wọn waa ke si awọn ijọba ipinlẹ mejeeji lati tete gbe igbesẹ tọ ileri ti wọn ṣe.

Leave a Reply