Lori ọrọ ti ko to nnkan, Ọpẹyẹmi ti iya agbalagba lulẹ, niyẹn ba gbabẹ ku l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Nibi ti wọn ba ti n gbadura pe k’Ọlọrun ma jẹ ka ba ẹni ti iku rẹ ti sun mọ itosi ja, afi keeyan tete maa ṣami o. Ọmọbinrin ẹni ọdun mẹrindinlogun kan, Ọpẹyẹmi Adudu, ti ba iya agbalagba kan ja lori ọrọ omi lasan, bo si ṣe ti iya naa niyẹn ṣubu lulẹ, ti ko le dide mọ, o gbabẹ lọ sọrun ni.

Ọmọbinrin naa ti wa lakata awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo bayi lori ẹsun pe o ṣeku pa iya agbalagba kan ti wọn porukọ rẹ ni Medinat Aliu, ninu ile kọju-si-mi ki-n-kọju-si-ọ, tawọn mejeeji jọ n gbe laduugbo Iṣọlọ, niluu Akurẹ.

ALAROYE gbọ pe iwẹ ni Ọpẹyẹmi kọkọ lọọ wẹ laaarọ ọjọ naa ninu baluwẹ kan ṣoṣo to wa ninu ile ọhun. Bo ṣe wẹ tan lo tun gbe rọba nla kan, to si mori le idi kanga to wa nitosi ile ti wọn n gbe lati pọnmi.

Bi ọmọbìnrin naa ti n pọnmi lọwọ ni wọn ni omi to wa lara irun ori rẹ n ro sinu kanga. Eyi ni iya ẹni ọdun mejilelaaadọta ọhun ri nibi to duro si to fi pe akiyesi rẹ si i pe ohun ti ko bojumu rara ni bi omi ara rẹ ṣe n ro da sinu kanga kan ṣoṣo ti ọpọlọpọ awọn eeyan ti n pọnmi laduugbo.

Nigba to si kọ ti ko da mama agbalagba ọhun lohun ni wọn lo sun mọ ọn nibi to bẹrẹ si ko le fa a kuro lẹgbẹẹ kanga naa. Nibi ti wọn ti n fa ọrọ yii mọra wọn lọwọ ni Ọpẹyẹmi ti fibinu ti iya oniyaa lulẹ, bi iya naa si ṣe balẹ bayii ni ko mira mọ, o gbabẹ sọda sọrun alakeji.

Kiakia lawọn araadugbo ti fi iṣẹlẹ ọhun to awọn agbofinro leti, tawọn yẹn si waa fi pampẹ ofin gbe ọmọbinrin naa lọ si teṣan wọn fun ifọrọwanilẹnuwo.

ALAROYE gbọ pe awọn ẹbi oloogbe ọhun ti sinku iya ọhun nilana ẹṣin Musulumi, nigba ti Ọpẹyẹmi ṣi wa ni ahamọ awọn ọlọpaa.

Leave a Reply