Lucky ran awọn ole si ṣọọbu ọga ẹ l’Agọ-Iwoye, gbogbo wọn ni wọn ko sọwọ ọlọpaa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọwọ awọn ọlọpaa Agọ-Iwoye, nipinlẹ Ogun, ti tẹ ọmọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Lucky Otuonye, ẹni to ran awọn gende meji mi-in, Chinedu Peter ati Matthew Igwe, lati waa fọ ṣọọbu ọga rẹ, ti wọn si ji tẹlifiṣan ti wọn n pe ni Plasma lọ ni ṣọọbu naa.

Ko sẹni to kọkọ mọ pe Lucky mọ nipa iṣẹlẹ yii, nitori awọn to waa jale lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keje naa, tun fi ọbẹ gun un lọwọ ki wọn too gbe tẹlifiṣan ọhun lọ.

Awọn ọlọpaa ko ri awọn to ṣiṣẹ naa mu lẹyin ti wọn gba ipe ti wọn si lọ sibẹ, Lucky ti wọn ṣe leṣe nikan ni wọn ba ti awọn eeyan rẹ si gbe e lọ sọsibitu.

Nitori ati ri awọn to ṣiṣẹ naa mu, awọn ọlọpaa ta awọn teṣan yooku to wa nitosi lolobo nipa ohun to ṣẹlẹ yii, ko si pẹ pupọ sasiko naa ni awọn ọlọde adugbo kofiri awọn meji ti wọn gbe tẹlifiṣan Plasma dani ninu paali ni Awa-Ijẹbu, bi wọn ṣe ta awọn ọlọpaa lolobo niyẹn.

Awa-Ijẹbu naa lawọn ọlọpaa ti mu awọn meji  yii, Chinedu ati Matthew. Wọn jẹwọ pe loootọ lawọn lọọ jale ni ṣọọbu ti wọn ti n ta nnkan eelo ile bii tẹlifiṣan l’Agọ-Iwoye, tawọn si tun gun ọmọ to n ba wọn taja nibẹ lọbẹ.

Wọn ni ṣugbọn awọn ko deede lọ sibẹ, Lucky ti ọga rẹ fi si ṣọọbu gan-an lo ni kawọn waa ja ṣọọbu naa lole. Chinedu ati Matthew sọ pe ajọmọ awọn ati Lucky ni, n ni wọn ba kuku lọọ gbe Lucky naa, wọn ju awọn mẹtẹẹta si gbaga.

Awọn ọlọpaa gba tẹlifiṣan naa lọwọ wọn, bẹẹ ni wọn tun gba ọkada Bajaj kan ati ọbẹ ti wọn fi gun Lucky lọwọ wọn.

Wọn yoo too foju ba kootu gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe wi. O ni aṣẹ ti ọga awọn, CP Edward Ajogun, pa niyẹn.

Leave a Reply