Ogundoyin tu gbogbo igbimọ awọn aṣofin ipinlẹ Ọyọ ka

Ọlawale Ajao, Ibadan

Olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Ọnarebu Debọ Ogundoyin, ti tu gbogbo igbimọ ile naa ka.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii lo kede igbesẹ naa lasiko ipade awọn aṣofin ipinlẹ ọhun.

Lẹyin ipade yii, ọga awọn ọnarebu naa ko fọrọ sabẹ ahọn sọ, o ni “Latoni lọ mọ tu gbogbo igbimọ ileegbimọ aṣofin yii ka loju-ẹsẹ.

Tẹ o ba gbagbe, oṣu kẹfa, ọdun 2019, ni wọn yan awọn igbimọ yii lẹyin ti wọn bura fun awọn aṣofin naa lẹyin idibo to gbe kaluku wọn wọle.

Ogundoyin ni o ṣe pataki ki awọn tu igbimọ yii ka, ki ileegbimọ naa le ṣiṣẹ rẹ bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.

O fi kun un pe igbesẹ yii ki i ṣe nnkan toju ko ri ri ninu ileegbimọ aṣofin gbogbo kaakiri orileede yii.

Leave a Reply