Makinde fẹẹ fi awọn to n tọrọ baara to ko kuro loju titi n’Ibadan sẹnu iṣẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Mẹsan-an ninu awọn to n tọrọ baara nigboro Ibadan nijọba ipinlẹ Ọyọ ti palẹmọ kuro loju titi l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, o ni ko saaye fun agbe ṣiiṣe nipinlẹ yii mọ.

Alakooso ọrọ ayika atawọn ohun alumọọni nipinlẹ Ọyọ, Dokita Abdullateef Idowu Oyeleke, lo fidi iroyin yii mulẹ lẹyin eto ipalẹmọ awọn oníbáárà nigboro Ibadan.

Dokita Oyeleke sọ pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ṣeto bayii lati palẹ gbogbo awọn to n tọrọ owo nibi gbogbo kaakiri ipinlẹ Ọyọ mọ nitori ipa ti awọn eeyan naa n ko lori itankalẹ ẹgbin ati ajakalẹ arun ki i ṣe kekere.

O ni ni General Gas, laduugbo Akobọ, n’Ibadan, ni ikọ amúṣ́ẹ́ṣe ti oun kó sòdí ti ko awọn eeyan mẹsẹẹsan ọhun nibi ti wọn ti n tọrọ owo lẹgbẹẹ titi.

Kọmiṣana yii sọ siwaju pe “Awọn oníbáára ki i bikita nipa imọtoto ati ilera wọn. Nipa iru igbesi aye bẹẹ, aisan ki i jinna si pupọ ninu wọn, wọn si maa n ko o ran awọn eeyan.

“Iyẹn nikan kọ, oriṣiiriṣii nnkan aburu bii ifipabanilopọ, ijinigbe, ìfiniṣètùtù, ati bẹẹ bẹẹ lọ lo maa n ṣẹlẹ si awọn eeyan yii.

“Ọna to daa ju lọ lati yọ wọn ninu awọn ajaga yii ni lati ko wọn kuro loju titi, ka si kọ wọn niṣẹ ọwọ to le maa mowo wọle fun wọn lẹyin ta a ba ti kọkọ pese eto ilera to peye fun wọn.”

O waa gba awọn ara ipinlẹ naa niyanju lati maa mu eto imọtoto ara ati ayika wọn ni pataki lati dena ajakalẹ arun lawujọ.

Inu ọgba ajọ to n ri si ìpamọ́ ofin eto imọtoto ayika l’ALAROYE gbọ pe wọn ko awọn oníbáárà ọhun lọ. Inu ọfiisi kan nibẹ ni wọn n sun titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Leave a Reply