Makinde fọwọ si Lekan Balogun gẹgẹ bii Olubadan tuntun

Jọkẹ Amọri

Ọsan ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, fọwọ si Sẹnatọ Lekan Balogun gẹgẹ bii Olubadan ilẹ Ibadan kejilelogoji.

Eyi waye pẹlu iwe ti awọn igbimọ Olubadan kọ lati fa Balogun kalẹ gẹgẹ bii Olubadan tuntun.

Ninu atẹjade ti Akọwe iroyin gomina, Taiwo Adisa, fi sita lo ti ni gomina ki Olubadan tuntun naa ku oriire, o si gbadura pe igba rẹ yoo tura.

Makinde ni, ‘Inu mi dun lati kede iyansipo Lekan Balogun gẹgẹ bii Olubadan kejilelogoji ilẹ Ibadan. Ikede yii wa ni ibamu pẹlu ilana ti wọn fi n jọba nilẹ Ibadan, eyi to da yatọ si tibikibi.

‘Lorukọ ijọba ati gbogbo eeyan daadaa nipinlẹ Ọyọ ni mo fi n ki Olubadan tuntun yii pe igba rẹ yoo kun fun alaafia ati itẹsiwaju ti ko lẹgbẹ.’

Leave a Reply