Makinde ṣeleri iranwọ fawọn oniṣowo ti ina ba dukia wọn jẹ n’lsọ paati n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti ṣeleri iranlọwọ fawọn ontaja ti dukia wọn ṣegbe sinu ijamba ina to waye lọja Ararọmi, l’Agodi, n’Ibadan.

Lasiko abẹwo ti Gomina Makinde ṣe si ọja yii lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde yii, lo ṣeleri ọhun.

Aarẹ ẹgbẹ awọn oniṣowo ọja naa, tawọn eeyan tun mọ si ọja Isọ paati, l’Agodi Geeti, n’Ibadan, Alhaji Moruf Ọlanrewaju, lo mu gomina atawọn igbimo ijọba rẹ to ko sodi lọ yika gbogbo ibi ti ina fọwọ ba ninu ọja naa.

Lẹyin abẹwo ọhun ni Makinde sọ pe “Mo wa sibi lasiko ipolongo ibo, mi o gbagbe awọn ileri ti mo ṣe nigba naa, mo ṣi n fi ọpọlọ ronu nipa ọna ta a le gba ran yin lọwọ. Mo ṣaa fi da yin loju pe ijọba wa maa ran yin lọwọ.

“Mo ri i bi nnkan tẹ ẹ padanu ninu ijamba ina yii ṣe pọ to. Ijọba yii ko ni i da ẹyin nikan da irora yii. A maa ṣeto awọn ọna ta a le gba ran yin lọwọ kiakia. Mo fẹ ki awọn adari ọja yii waa ri mi lọfiisi lọla (ọjọ Aje, Mọnde) ka jọ jiroro lori ọna ta a ba maa gbe e gba.

Ṣugbọn kinni kan wa ti mo fẹ ka ṣe. Mo ro pe o yẹ ka gbe ọja yii kuro nibi. Mo si fẹ ki ẹyin naa ronu nipa ẹ, nitori bi ibi ṣe wa yii, o ti fun pupọ ju, mo ri i pe ko gba yin mọ, iyẹn lo si jẹ ki ijamba yii lagbara to bayii. Iyẹn ni mo ṣe ro pe o yẹ ka gbe ọja yii lọ sibomi-n to maa le gba yin daadaa.

“Ṣugbọn nnkan ta a gbọdọ jọ sọ kunna laarin ara wa ni, nitori mi o fẹ ki iru ajalu bayii tun waye mọ. Ti iru ẹ ko ba si ni i waye mọ, gbogbo wa la ni lati jọ jokoo, ka jọ fikun lukun lori ba a ṣe maa ṣe e.”

“Lori ohun ta a maa ṣe lati fi ran yin lọwọ, mo fẹ kawọn adari ọja yii kọ orukọ awọn to ni ṣọọbu nibi ti ijamba ina yẹn ti ṣẹlẹ waa fun mi, ka le tete ṣeto iranlọwọ to ba yẹ fun wọn.”

 

 

 

Leave a Reply