Florence Babaṣọla, Osogbo
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe janduku meje lawọn ti fi pampẹ ofin gbe lori wahala to bẹ silẹ lasiko ti wọn fẹẹ fi agidi gba garaaji ọkọ-ero to wa ni Gbọngan Branch 2, ninu eyi ti wọn ti ṣe igbakeji alaga ibẹ, Fẹmi Ọmọniyi, leṣe.
Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ọjọ diẹ ti awọn agbebọn kan ji Igbakeji alaga ẹgbẹ awakọ NURTW nipinlẹ Ọṣun, Kazeem Ali, gbe niluu rẹ, Apomu, lẹyin ti wọn ṣa a ladaa ninu mọto, ti ko si sẹni to mọ’bi to wa titi digba ti a n koroyin yii jọ.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣe ṣalaye, aago mọkanla aabọ aarọ Ọjọbọ, Wẹsidee, ọsẹ yii, lawọn janduku ti Nurudeen Sule jẹ adari wọn ọhun ya wọ garaaji ti Ọmọniyi wa.
Bi wọn ṣe debẹ ni wahala bẹrẹ, wọn ṣa Ọmọniyi ladaa lori, bẹẹ ni ọpọlọpọ awọn dẹrẹba fara pa nibẹ, ti gbogbo awọn eeyan agbegbe ibẹ si n sa kijokijo kaakiri.
Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe bi awọn ṣe gbọ ni awọn lọ sibi iṣẹlẹ naa, ti ọwọ si tẹ awọn janduku meje nibi ti wọn fara pamọ si pẹlu Nurudeen ti gbogbo eeyan mọ si Biggy.
O ni awọn ọlọpaa ri ada ti wọn fi huwa laabi naa gba lọwọ awọn afurasi, wọn gbe Ọmọniyi lọ si ọsibitu kan niluu Ipetumodu, nibi to ti gba itọju, ati pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.