Faith Adebọla
Epe kabiti-kabiti lawọn eeyan n rọjo sori awọn olubi ẹda mẹta kan tawọn ẹṣọ alaabo Amọtẹkun ṣafihan wọn n’Ibadan, nipinlẹ Ọyọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, latari bi awọn afurasi ọdaran naa ṣe jẹwọ iku oro ti wọn fi pa baba arugbo ẹni ọdun mẹtalelaaadọrin kan, Adebisi Adeniyi, wọn bẹ baba naa lori, wọn tun jo ori ọhun nina bii asejẹ.
Orukọ awọn ọdaju afurasi ọdaran naa ni Muraina Ismail, Ọlalekan Muyideen ati AbdulRasheed Ọlanrewaju.
Bi wọn ṣe jẹwọ fawọn oniroyin lasiko afihan to waye lolu-ile awọn ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ọyọ, eyi to wa laduugbo Dandaro, niluu Ibadan, wọn ni ọjọ Aiku, Sunday to kọja yii, lawọn ji baba arugbo naa gbe loju ọna Amuloko si Akanran, n’Ibadan.
Ismail sọ pe Ọlanrewaju lo fẹẹ ṣoogun owo, ẹgbẹrun marundinlogoji lo si ko kalẹ pe kawọn fi ba oun wa ori eeyan toun maa lo lati fi ṣoogun owo ojiji ọhun. O lawọn wa eeyan titi, awọn ko tete ri, ni ọkan lara awọn, Muyideen, ba mu baba arugbo naa wa pe kawọn kuku bẹ ori ẹ ta.
O niṣe lawọn kọkọ fi ọbẹ dumbu baba naa bii ẹran, lẹyin naa lawọn waa fi ada ge ori ọhun peu.
“Emi ni mo di baba naa lẹsẹ mu, Aafaa Muyideen lo di i lori mu, oun lo si dumbu rẹ, ko too fi ada ge e ja lẹyin ti baba naa ti ku,” Ismail lo jẹwọ bẹẹ.
Muyideen ni tiẹ jẹwọ pe kẹkẹ Marwa loun n wa lọ lọjọ toun ri baba naa lẹgbẹẹ ọna, o ni oogun agbẹnugọngọ loun fi ahọn ba, toun fi ba baba naa sọrọ pe ko wọle sinu kẹkẹ oun, baba naa ko si ba oun jiyan, o ṣe bẹẹ ni. O ni bawọn ṣe ge ori naa tan loun ti gbe e fun Ọlanrewaju to fẹẹ lo o, awọn si gbe iyoku ara oloogbe naa sinu apo idọhọ kan, awọn fi aṣọ bẹẹdi di i daadaa, lawọn ba lọọ sin in sẹyinkule ile ti ọkan ninu awọn n gbe loru.
Muyideen tun jẹwọ pe ọmọ tuntun ki i ṣe akọpa ajẹ foun, o ni oun ti maa n ta ori eeyan fawọn ti wọn ba nilo ẹ tẹlẹ, ẹgbẹrun lọna ogoji naira (N40,000) si ẹgbẹrun lọna ọgọta naira (N60,000) loun maa n ta ori kan.
O tun sọ pe obinrin kan to n gbe adugbo naa lo kọsẹ de ibi tawọn sin ageku ara baba arugbo naa si, ara fu u, lo ba ke sawọn agbaagba adugbo naa, ni wọn fi fọrọ naa to awọn ẹṣọ Amọtẹkun leti.
Ọlanrewaju ni tiẹ jẹwọ pe loootọ loun fẹẹ ṣoogun owo, oun si sọ fun wọn pe ki wọn ba oun wa ori, ṣugbọn ki i ṣe ori tutu, ori gbigbẹ loun fẹẹ lo, oun o si sọ fun wọn pe ki wọn lọọ paayan foun.
O tun ṣalaye pe nigba ti wọn gbe ori oloogbe naa foun pe eyi tawọn ri niyẹn, oun gba a bẹẹ lọwọ wọn, oun si gbe ori naa sinu ikoko apẹ kan, ibẹ lo loun ti sun un deeru.
Ọkunrin naa fi ajoku ori baba arugbo ọhun han awọn oniroyin.
Ọga agba awọn ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ sọ pe iwadii ṣi n lọ lori ọrọ yii, ati pe laipẹ lawọn yoo fa awọn olubi ẹda yii le awọn agbofinro lọwọ.