Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Oloye Rashidi Ladọja, gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan, ti sọ pe oun ki i ṣe oloṣelu mọ, (partisan politics) o ni o loju ohun ti oun le sọ lori ọrọ oṣelu Naijiria.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni Ladọja sọrọ naa nigba to ṣabẹwo si Oloye Alani Bankọle, iyẹn Baba Dimeji Bankọle, ti wọn si jọ tilẹkun mọri ṣepade fun wakati mẹrin gbako.
Lẹyin ipade naa lawọn akọroyin gbiyanju lati gbọ ohun to gbe Ladọja wa si Abẹokuta lati Ibadan, ṣugbọn ọkunrin naa ni ki i ṣe ọrọ oṣelu lo gbe oun wa, ki i ṣe ọrọ ipo tabi ti Naijiria, o loun kan waa ki Bọọda oun Bankọle gẹgẹ bo ṣe yẹ ko ri naa ni.
Nigba to n dahun ibeere mi-in lori oṣelu, gomina tẹlẹ naa rọ awọn ọdọ orilẹ-ede yii lati mura si oṣelu, ki wọn ri i daju pe wọn kopa nibẹ, paapaa bi ibo ọdun 2023 ṣe n sun mọle.
O tẹsiwaju pe Bọọda oun Alani Bankọle toun waa ba l’Abẹokuta yii naa ti jawọ ninu oṣelu, awọn ti jọ fi i silẹ fawọn ọdọ lati maa tẹsiwaju.
Lori bi Naijiria ṣe ri lasiko yii, paapaa lagbo oṣelu, Oloye Rashidi Ladọja ni oun ko ni ohunkohun lati sọ, nitori oun ki i ṣe oloṣelu mọ.
Bakan naa ni Oloye Alani Bankọle sọ pe oun ko ni ohunkohun lati sọ lori bi nnkan ṣe n lọ ni Naijiria lọwọ, nitori oun ti fi ọwọ oṣelu ti sibi kan.
Ṣugbọn ohun ti awọn awoye oṣelu n sọ nipa ipade awọn agba meji yii ni pe ko le ṣẹyin idibo ọdun 2023.
Wọn ni kinni kan ni wọn n roko ẹ silẹ ki idibo naa too de, pẹlu bo ṣe jẹ ko ti i ju ọjọ kẹfa ti Gomina Yobe, Mai Mala Buni, pẹlu awọn gomina meji mi-in ṣepade pẹlu awọn agbaagba kan nilẹ Yoruba.