Mi o le lọ si ṣọọṣi tabi mọṣalaaṣi, Ogun lo n ṣe ohun ti mo fẹ fun mi—Agbẹdẹ Afuyẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Agbẹdẹ Ogunṣina Afuyẹ ko pe meji n’Itoko, l’Abẹokuta, ṣugbọn ki i ṣe n’Itoko nikan lọkunrin naa ti gbajumọ, kaakiri Abẹokuta ni.

Yatọ si pe ọkunrin ti wọn n pe ni Afuyẹ yii n rọ ọkọ ati ada pẹlu awọn nnkan mi-in ti wọn n fi irin ṣẹ, o tun maa n ba awọn eeyan bọ Ogun (Ogun Federal ni wọn pe e, wọn ni gbogbo ibi ni wọn ti n waa bọ ọ lawọn ṣe n pe e bẹẹ)

Eeyan le ro pe bibọ Ogun ti kasẹ nilẹ lasiko yii, ṣugbọn ti tọhun ba de Agbẹdẹ Afuyẹ, to ri i bawọn eeyan ṣe n mu oriṣiiriṣii ẹranko waa bọ Ogun, yoo mọ pe iṣeṣe ko rebi kan. ALAROYE de Agbẹdẹ Afuyẹ n’Itoko, eyi lohun t’ọkunrin naa ba wa sọ.

‘‘Ọrukọ mi ni Ogunṣina ọmọ Afuyẹ. Ọwọ baba mi ni mo ti jogun iṣẹ yii, ti mo ba ti de lati ileewe nigba ti mo wa ni kekere ni mo maa n jokoo ti wọn ti mo fi kọ ọ.

O ti pe ọgbọn ọdun ti mo ti n ba iṣẹ yii bọ. Ọjọ iwaju iṣẹ yii dẹ daa pupọ, nitori nigba tawọn baba temi n ṣe e, ko daa to bayii, o ṣi maa daa ju bayii lọ lẹyin tiwa naa.

Mo n ba awọn eeyan bọ Ogun, ki i ṣe pe irin nikan ni mo n rọ. Mo maa n lọ s’Ekoo lọọ ba wọn b’Ogun, owo nla ni mo dẹ maa n gba bọ.

‘’Ti aje ba wa daadaa, mo maa n pa to ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira (100,000) lojumọ. Owo ipabi Eṣu la maa n kọkọ gba, ẹgbẹrun marun-un niyẹn. Awọn to wa n bọ Ogun maa n mu aja wa, wọn n mu adiẹ wa, wọn n mu ẹlẹdẹ naa wa, koda, wọn maa n mu ijapa wa. A dẹ maa gbowo iṣẹ pe a ba wọn bẹ ẹ s’Ogun.

‘‘Bi mo ṣe wa yii, Ogun n ṣe ohun ti mo fẹ fun mi, beeyan ba niṣoro, wọn aa ni ko lọọ bọ Ogun lọdọ Afuyẹ. To ba dẹ ti ṣe e, ọna aa la, Ogun n ṣe e.

‘‘Mi o le lọ si ṣọọṣi tabi mọṣalaaaṣi, bii pe mo yọjuran lọ ni, nigba to jẹ gbogbo ohun ti mo fẹ l’Ogun n ṣe fun mi nibi, ti mo ba dẹ ba awọn eeyan bọ Ogun, ohun ti wọn ba fẹ maa n bọ si i, kin ni mo waa fẹẹ maa lọ si ṣọọṣi tabi mọṣalaaṣi fun.

Looootọ, baba mi kirun ku ni tiwọn ni, ṣugbọn emi o kirun ri, ohun ti mo maa ṣe ku ni mo gbe dani yii, ti mo dẹ maa fi le ọmọ lọwọ.

Awọn pasitọ kan gan-an maa n waa bọ Ogun lọdọ wa laaarọ ki wọn too lọ si ṣọọṣi, ti wọn ba ti sọ fun un pe ko lọọ bọ ọ lati dena Eṣu, ki wahala ma baa ṣẹlẹ. Ko kuku ni i de ṣọọṣi ko lọọ sọ fun wọn pe oun ti bọ Ogun, aarọ kutu lo ti maa wa sibi ta a ti maa ba a bọ ọ.

Ṣe ẹ tiẹ ri Ogun tiwa yii, Ogun Fẹdira ni (Federal) iyẹn ni pe gbogbogboo ni. Ko sibi ti wọn ko ti n waa bọ ọ. Wọn n bọ ọ lati ilu oyinbo bo ṣe wa yii, lati Amẹrika ati London. Wọn maa fowo ranṣẹ, a maa ba wọn bọ ọ nibi, a dẹ maa fi fọto ẹ ranṣẹ si wọn.

Mo ṣi ba ẹnikan bọ ọ laipẹ yii lẹyin to fowo ranṣẹ, mo dẹ fi fọto ẹ ranṣẹ si i.

Ohun ti mo fẹẹ sọ fawọn eeyan wa ni pe ki wọn ma gbagbe iṣẹṣe, Ọlọrun wa loootọ ṣugbọn a ko gbọdọ fi awọn ohun ta a ba laye silẹ, o yẹ ka maa ṣe wọn lọ ni.

ALAROYE ba obinrin alakọwe kan to gbe mọto waa bọ Ogun yii lọdọ Agbẹdẹ Afuyẹ, Abimbọla Yusuf lorukọ ẹ. Obinrin giga rọgbọdọ naa sọ pe wọn ni koun waa bọ Ogun loun ṣe wa, oun ko le ma bọ ọ lẹẹẹmeji loṣu, oun si n ri iṣẹ rẹ lara oun.

Abimbọla to mu akukọ adiẹ waa bọ Ogun naa sọ pe bi ṣọọṣi tabi mọṣalaaṣi ba ya, oun n lọ, ṣugbọn Ogun yii naa ko ṣee ma bọ nitori iyẹn ni tiwa nilẹ Yoruba, atọhunrinwa lẹsin Kristẹni ati ti Musulumi.

Leave a Reply