Mi o lodi sawọn to lọọ ri Ọṣinbajo, ṣugbọn o nidii temi o fi lọ– Mr. Makaroni

Faith Adebọla, Eko

 Gbajugbaju adẹrin-in poṣonu ori ẹrọ ayelujara nni, Debọ Adedayọ, tawọn eeyan mọ si Mista Makaroni ti sọ pe ahesọ lọrọ tawọn eeyan n gbe kiri nipa idi toun ko fi pẹlu awọn ẹlẹgbẹ oun to lọọ ṣabẹwo si Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, l’Abuja, lọsẹ to kọja yii, o loun ko lodi si bi wọn ṣe lọ o, ṣugbọn o nidii pataki toun ko fi lọ.

Ninu alaye to ṣe nigba to n ba AKEDE AGBAYE sọrọ, Debọ ni lara orirṣiiriṣii ahesọ tawọn eeyan kan n sọ kiri ni pe wọn o fọrọ abẹwo naa to oun leti ni, awọn mi-in si sọ pe wọn fi to oun leti, pe oun tiẹ lọ paapaa, ṣugbọn fọto loun o ba wọn ya, tabi boya nitori oun o ki i ṣalatilẹyin fun ijọba to wa lode yii ni.

Debọ waa tanmọlẹ sọrọ naa, o ni ki i ṣe ijọba lo pe awọn alawada wọnyi, o ni ajọ aladaani kan, Nigeria Skits Industry Awards, eyi ti Ọnarebu Bimbọ Daramọla ṣagbatẹru ẹ lo wa nidii rẹ. O ni wọn sọ foun nipa abẹwo naa, ṣugbọn oun kọ lati lọ tori ọwọ oun di fun awọn iṣẹ kan toun n ya lọwọ, ati pe ko sohun tuntun toun fẹẹ sọ funjọba ati awọn alaṣẹ ti wọn o ti i gbọ nipa ẹ tẹlẹ.

“Idi ti mi o fi lọ ko le rara, gẹgẹ bii ọmọ orileede yii, inu mi o dun sawọn olori wa wọnyi, mi o si fẹẹ ba wọn da ohunkohun pọ. Ko sohun to buru nibẹ tawọn mi-in ba lero pe nnkan le yipada si daadaa tawọn ba jokoo pọ pẹlu awọn alaṣẹ o, wọn gbiyanju ẹ wo ni, ko dẹ si idi lati ta ko wọn tori ẹ.

‘‘Ki i ṣe gbogbo awọn to lọ yẹn naa lo jẹ tori owo ni wọn ṣe lọ, mo tiẹ le gba ẹri awọn kan jẹ lara wọn, mi o si ta ko wọn fun lilọ ti wọn lọ, bẹẹ ni mi o fẹ kẹyin ololufẹẹ wọn kọyin si wọn tabi sọrọ si wọn.

Ṣugbọn ni temi, gbogbo ohun ti mo fẹ ni mo ti n sọ ninu awọn atẹjade mi, lori ayelujara, ati nibikibi ti mo ba ti lanfaani lati sọrọ. Ko sohun meji to jẹ aniyan mi ju pe ki Naijiria dara lọ, ki irẹjẹ dopin, ki igbaye-gbadun si wa fun tẹru tọmọ, ko ma jẹ ọdọ awọn kan ni nnkan ti maa rọṣọmu.

‘‘Tawọn oloṣelu ba lawọn fẹẹ ba mi sọrọ, tabi awọn fẹẹ gbe iṣẹ fun mi, mo maa n sọ fun wọn pe ki wọn jẹ ka pade ni gbangba walia, nibi tawọn oniroyin maa wa ni, ti ma a le sọ ero ọkan mi bo ṣe ri lara mi, ki i ṣe ni kọlọfin. Ṣebi gbangba ni wọn ti maa n waa ba wa ti wọn ba fẹẹ polongo ibo, ti wọn maa maa tẹwọ si wa, wọn aa jẹ akara pẹlu wa nigba yẹn, ki lo waa de ti wọn maa ni ka waa ba awọn nibi kan ni, emi o ṣe iru ẹ.

‘‘Mi o sọ pe ẹni pipe ni mi o, mi o si sọ pe mo daa ju awọn ẹlẹgbẹ mi lọ, ẹ le ro pe ọmọ lile ni mi loootọ, bẹẹ ni, ṣugbọn ki Naijiria ti daa fun mẹkunnu lemi n ja fun, mo si n lo ẹnu mi, ohun mi, ati ẹbun t’Ọlọrun fun mi lati ja fun un, bo tilẹ jẹ pe atako ni wọn fi n san an pada, niṣe nijọba fiya jẹ mi tori ẹ, ṣugbọn mi o wọri.”

Ọpọ awuyewuye lo ti n lọ lori atẹ ayelujara lori abẹwọ tawọn adẹrin-in poṣonu naa ṣe sọdọ Aarẹ, eyi to mu ki Debọ ṣalaye ara ẹ, ọpọ eeyan bẹnu atẹ lu awọn to lọọ ṣabẹwo ọhun, ti wọn si n gboṣuba ‘kare lae’ fun Mista Makaroni ti ko dara-pọ mọ wọn, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan naa ti n ṣalaye ara wọn fawọn ololufẹ wọn pe ki i ṣe ojuure tabi owo lawọn ba lọ.

Lara awọn to ṣabẹwo naa ni Ayọ Ajewọle (Wolii Agba), Adeyẹmi Ẹlẹṣọ, Adebamiro Adeyanju (Mr. Hyenana), Maryam Apaokagi (Taaooma) ati Josh Alfred (Josh2funny).

Leave a Reply