Mi o ni ẹnikẹni sinu lori idajọ ẹwọn gbere ti wọn da fun ọkọ mi- Ẹfanjẹliisi Abisọla

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ

Ara ọtọ patapata ni isin ọjọ isinmi to kọja yii jẹ nile-ijọsin Sọtitobirẹ, eyi to wa lagbegbe Ọshinlẹ, niluu Akurẹ, pẹlu bawọn ọmọ ijọ naa ko ṣe le pa idunnu wọn mọra latari idajọ kootu Kotẹmilọrun to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, pe ki wọn tu oludasilẹ ọọi ọhun, Alfa Samuel Babatunde, silẹ ninu ọgba ẹwọn to wa lati bii ọdun meji sẹyin.

Bo tilẹ jẹ pe Wolii Alfa i wa lọgba ẹwọn Olokuta, ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni wọn lo ṣee ṣe ki wọn ṣẹṣẹ yọnda rẹ patapata lẹyin ti agbẹjọro rẹ ba ti pari gbogbo igbesẹ to yẹ ko gbe lori ọrọ ominira rẹ. Sibẹ, ijo ati ayọ lawọn olujọsin ọhun fi bẹrẹ isin wọn ọjọ naa lati ibẹrẹ titi de opin.

 

Eyi ni yoo jẹ igba akọkọ tawọn ọmọ ijọ Sọtitobirẹ yoo fi iru ayọ bẹẹ han lati inu ou kẹwaa, ọdun 2019, tiṣẹlẹ ọmọ ọdun kan to sọnu ninu sọọsi ọhun ti waye.

Iyawo oludasilẹ ijọ naa, Ẹfanjẹliisi Abisọla Alfa, to dari ijọsin ọhun fi ẹmi imoore rẹ si Ọlọrun han fun bi ile-ẹjọ ṣe tu ọkọ rẹ silẹ lasiko to da bii ẹni pe ireti tí fẹẹ pin bẹẹ lo fi da awọn eeyan loju pe oun ko ni i di ẹnikẹni sinu lori iṣẹlẹ naa.

Abilekọ Alfa rọ awọn ọmọ ijọ wọn lati ma ṣe binu tabi ki wọn ba ẹnikẹni ja lori gbogbo ipenija ti awọn ti n la kọja fun bii ọdun meji sẹyin.

 

Nigba to n pari ọrọ iyanju rẹ, funra rẹ lo saaju awọn olujọsin ọhun lati gbadura fun titete ri ọmọdekunrin to sọnu ọhun, Gold Kọlawọle, bakan naa lo tun ni ki wọn gbadura pe ki airi gbogbo awọn to wa nidii bi ọmọ naa ṣe di awati tu laipẹ laijinna.

 

Ọkan ninu awọn agba ijọ naa, Alagba Babade Oluwalayọmi, to b’ALAROYE sọrọ ni ọpẹ nla lawọn n fi fun Ọlọrun pe o gbọ igbe ati ẹbẹ awọn lori itusilẹ Wolii Alfa.

Ijọba ipinlẹ ti ni awọn i n ronu lori igbesẹ to yẹ ki awọn gbe lori bi ile-ẹjọ Kotẹmilọrun ṣe da Wolii Alfa Babatunde silẹ ninu ijokoo wọn to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.

 

Kọmisanna feto idajọ to tun jẹ olupẹjọ, Ọgbẹni Charles Titiloye, lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lori ọrọ idajọ naa.

Titiloye ni oun ko ti i le sọ ni pato ohun tijọba fẹẹ ṣe lori ọrọ ẹjọ naa, o ni o digba ti awọn ba pari ayẹwo tí awọn n ṣe lọwọ si iwe agbekalẹ idajọ naa ki oun too le sọrọ nipa igbesẹ ti awọn fẹẹ gbe.

Leave a Reply