Mi o ni i gbowo lọwọ ẹnikẹni lati fun Fulani ni ilẹ ifẹranjẹko l’Ondo-Akeredolu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina Rotimi Akeredolu ti ni ko si aaye ilẹ kankan ti oun le ya sọtọ fawọn Fulani lati maa ṣiṣẹ ẹran ọṣin dida wọn nipinlẹ Ondo.

Arakunrin ni ijọba ipinlẹ naa ko ti i gbowo lọwọ ẹnikẹni, bẹẹ ni oun ko ṣetan ati gbowo lọwọ awọn Fulani nitori ọrọ ilẹ ifẹranjẹko.

Aketi ni ko si ninu eto ijọba ti oun n dari lati ya ilẹ kan sọtọ fun awọn darandaran nitori pe igbesẹ ọtọ patapata nijọba n gbe lọwọ lori ọrọ nnkan ọṣin nipinlẹ Ondo.

O ni lati igba ti oun ti buwọ lu abadofin ifẹranjẹko ti gbogbo awọn gomina ẹkun Guusu fẹnuko le lori lọjọ kin-in-ni, osu kẹsan-an ọdun yii, lo ti deewọ fun awọn darandaran ki wọn maa daran wọn nita gbangba.

Akeredolu ni abadofin ifẹranjẹko ti oun ṣe ti fẹsẹ mulẹ labẹ ofin, eyi ti ko ni i ṣee yipada mọ.

Leave a Reply