Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina Gboyega Oyetọla ti ipinlẹ Ọṣun ti ṣeleri fawọn araalu pe ti wọn ba le fi ibo wọn gbe oun wọle fun saa keji lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje, ọdun yii, oun ko ni i ja wọn kulẹ rara.
Nibi eto kan ti ibudo to n ri si ọrọ ibaṣẹpọ laarin awọn araalu atijọba ṣagbekalẹ rẹ labule Ijimọ, nijọba ibilẹ Oriade, ni gomina ti sọrọ idaniloju yii.
Oyetọla, ẹni ti oludamọran pataki fun un lori ọrọ ibaṣẹpọ awọn araalu atijọba, Ọgbẹni Ọlatunbọsun Oyintiloye, ṣoju fun, sọ pe oun ti da majẹmu pẹlu Ọlọrun ati awọn araalu ti wọn gbe oun depo agbara lati mu ọrọ igbaye-gbadun wọn lọkun-un-kundun ni gbogbo igba.
Oyetọla ni ahesọ to jinna soootọ ni pe oun yoo dawọ gbogbo iṣẹ rere ti oun n ṣe kaakiri duro ni kete toun ba ti wọle fun saa keji.
O ni latigba ti oun ti di gomina, oun ko figba kankan ja awọn araalu kulẹ, bẹẹ ni oun ko si ni i yi iwa pada ti oun ba pada wọle.
Oyetọla ṣalaye pe lara awọn ileri ti oun ṣe fawọn araalu nigba ti oun di gomina loṣu kọkanla, ọdun 2018, ni pe oun yoo maa san owo-oṣu awọn oṣiṣẹ lẹkunun-rẹrẹ ati lasiko to yẹ, to fi kan owo ifẹyinti wọn.
O ni titi di asiko yii loun n mu awọn ileri naa ṣẹ, bẹẹ ni awọn oṣiṣẹ-fẹyinti n gba owo wọn lasiko.
Oyetọla ni oun tun dawọ le oniruuru awọn iṣẹ idagbasoke ni eto ẹkọ, eto ilera, atunṣe oju-ọna, ipese iṣẹ, fifun awọn araalu lounjẹ loṣooṣu ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Yatọ si biriiji nla to wa lorita Ọlaiya, eleyii ti wọn yoo ṣi fun lilo laipẹ yii, gomina ni aimọye oju-ọna nijọba oun n ṣe kaakiri ilu.
O ni ti wọn ba fun oun lanfaani lẹẹkeji, gbogbo awọn iṣẹ rere yii ko ni i dawọ duro rata, oun yoo si tun ṣe ju bẹẹ lọ.
Gomina waa rọ awọn araalu lati ma ṣẹ faaye gba awọn ọjẹlu lati tan wọn nitori wọn ti dan oun wo fun ọdun mẹrin, wọn si ri i pe oun dangajia.
Nigba to n sọrọ, Onijimọ ti Ijimọ, Ọba Samuel Ishọla Abe, gboṣuba fun gomina lori abẹwo naa, o ni ki gomina tẹ siwaju nitori abẹwo ọhun yoo mu ki ibaṣepọ to dara wa laarin ijọba ati awọn araalu.
Lẹyin ti Ọba Abe dupẹ lọwọ gomina fun oniruuru iṣẹ idagbasoke to n ṣe, o rọ ọ lati tubọ maa ṣi awọn ọna kaakiri igberiko, ki ipese ina ijọba wa, ki omi-ẹrọ si maa yọ daadaa.