Miliọnu kan aabọ ‘irẹṣi Tinubu’ ni wọn n ha lọwọlọwọ bayii nilẹ Hausa

Faith Adebọla, Eko

Pitimu lawọn eeyan lapa Oke-Ọya n ya bo awọn ibudo ti wọn ti n fi irẹsi tọrẹ lọfẹẹ, ‘Irẹsi Tinubu’ ni wọn pe e, ojoojumọ si ni wọn n ha irẹṣi ọfẹ naa, wọn ni ẹbun ti Aṣiwaju Bọla Tinubu fun  wọn lasiko aawẹ Ramaddan yii ni.

ALAROYE gbọ pe wọn ni ṣinkin ni inu awọn araalu n dun bi wọn ti n da girigiri lọọ gba ounjẹ ọhun, apo irẹsi kan fun idile kan, pẹlu aworan Bọla Tinubu ati akọle JAGABAN ti wọn kọ gadagba sara apo naa.

Nigba to n ṣe ifilọlẹ eto ọhun niluu Yola, ipinlẹ Adamawa, Ọgbẹni Dahiru Hammadikko sọ pe ki i ṣe Bọla Tinubu lo n ha irẹsi naa, o lawọn tawọn jẹ ọrẹ rẹ kaakiri awọn ipinlẹ mọkandinlogun ni apa Oke-Ọya lawọn fori kori, tawọn si ṣeto lati pin irẹsi naa fawọn eeyan lorukọ Tinubu, o lawọn fẹẹ fi pọn Tinubu le ni.

“Lonii, ọjọ Iṣẹgun, a n ṣefilọlẹ pinpin irẹsi fawọn ọmọ Naijiria lapa Ariwa nibi. Afojusun wa ni lati pin in fun ohun miliọnu kan aabọ eeyan, kaakiri awọn ipinlẹ Ariwa lo maa de, titi kan Abuja naa.

Ni Adamawa nibi, a maa pin irẹsi to ju ẹgbẹrun mẹwaa lọ, bẹẹ la si ṣe maa pin in kiri awọn ilu nla.

A fẹẹ fi pọn adari apapọ ẹgbẹ APC, Bọla Tinubu, le ni, fun bo ṣe lawọ, tori ẹ la ṣe tẹ orukọ ati aworan rẹ sara baagi irẹsi naa.

Leave a Reply