Miliọnu lọna ọgbọn naira lawọn to ji olori ọdọ n beere nipinlẹ Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Owo ti ko din ni miliọnu lọna ọgbọn naira (30m) ni awọn ajinigbe to ji olori ẹgbẹ ọdọ ti wọn n pe ni National Youth Council Of Nigeria(NYCN), l’Odogbolu, Ọgbẹni Ọlamilekan Okunuga, n beere bayii lọwọ awọn eeyan ọkunrin naa.

Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii ni awọn ajinigbe ọhun rẹburu mọto alakooso ọrọ ọdọ naa lasiko to n bọ lati ilu Ibadan. Agbegbe Ogere gan-an ni wọn ti kọ lu u, nipinlẹ Ogun. Wọn fi mọto rẹ to n gbe bọ silẹ sẹba ọna, wọn si gbe ọkunrin naa wọgbo lọ.

Nigba to n fidi ijinigbe naa mulẹ lọjọ Sannde ọsẹ yii, Alaga ẹgbẹ NYCN, Abduljabar Ayelaagbe, sọ ọ di mimọ pe irọlẹ ọjọ keji iṣẹlẹ naa ti i ṣe ọjọ Ẹti lawọn ọlọpaa sọ fawọn pe ọwọ ti ba ọkunrin kan to n wa mọto Okunuga kaakiri l’Ogijo.

O ni ọkunrin tawọn ọlọpaa mu naa ṣalaye pe oun ri awọn ajinigbe ọhun nigba ti wọn n gbe Okunuga wọgbo lọ, bi wọn si ti gbe e lọ tan loun pinnnu lati gbe mọto rẹ sa lọ ni toun. Ohun to jẹ kawọn ọlọpaa mu un niyẹn nigba ti wọn ri i pẹlu mọto naa.

Alaga NYCN naa sọ pe awọn ajinigbe ọhun ti kan sawọn ẹbi Okunuga, miliọnu lọna ọgbọn naira ni wọn si fẹẹ gba ki wọn too le fi i silẹ. O rọ awọn agbofinro lati jọwọ karamaasiki ọrọ yii, ki wọn si wa Ọlamilekan Okunuga jade.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni oun mọ pe awọn ajinigbe ji ẹnikan gbe l’Ọjọbọ naa, ṣugbọn oun ko mọ ẹni to jẹ tabi iru ipo to di mu.

Oyeyẹmi sọ pe awọn ti mu ẹnikan lori iṣẹlẹ ijinigbe yii, bẹẹ ni iṣẹ ṣi n lọ lati mu awọn yooku ti wọn tun lọwọ ninu ẹ.  

Leave a Reply