Ọdun marun-un ni Sunday yoo lo lẹwọn, eeyan mẹsan-an lo lu ni jibiti owo ile l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Abaniwale ni Sunday Ikoni, niluu Abẹokuta. Ṣugbọn ẹwọn ọdun marun-un ni ile-ẹjọ Majisireeti to wa n’Iṣabọ, l’Abẹokuta, ju u si bayii, nitori o gba miliọnu mẹrin din diẹ naira (3.9m) lọwọ eeyan mẹsan-an to n wale.

Ọjọ Ẹti to kọja yii ni Adajọ O. M Ṣomẹfun sọ ọ di mimọ pe gbogbo ẹri lo foju han pe Sunday lu awọn eeyan mẹsan-an naa ni jibiti, oun funra rẹ naa si pada jẹwọ pe loootọ loun gbowo naa lọwọ wọn lai fun wọn nile.

Agbefọba, Ọlakunle Ṣọnibarẹ, to ṣoju kootu lori ẹjọ yii ṣalaye pe laarin oṣu kẹsan-an to kọja yii ni olujẹjọ gba owo naa lọwọ awọn eeyan to waa ba a pe awọn n wa ile. O ni Ibara Housing Estate wa lara agbegbe ti Sunday loun yoo ba wọn wa ile ọhun si, ṣugbọn niṣe lo fowo kaluku wọn ṣararindin.

Diẹ ninu awọn eeyan ti Sunday Ikoni gbowo lọwọ wọn ree gẹgẹ bi Agbefọba Ṣọnibarẹ ṣe wi: Ọgbẹni Mark Taiwo (750,000), Ọgbẹni Ọdẹṣọmi Ṣẹgundo (500,000) ,Ọgbẹni Mohammed Bello (490,000) pẹlu awọn eeyan mẹfa mi-in, apapọ owo to gba naa si din diẹ ni miliọnu mẹrin ni.

Eyi lodi sofin ilẹ yii ati tipinlẹ Ogun ti wọn ṣe lọdun 2006, ijiya si wa fun un.

Niwọn igba ti olujejọ naa si ti loun jẹbi ẹ, adajọ ran an lẹwọn ọdun marun-un, tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun lọna igba ataabọ (250,000) lẹsẹkẹsẹ, iyẹn lẹyin to ba ti da gbogbo owo awọn to lu ni jibiti pada

Leave a Reply