Miliọnu marun-un Naira lawọn agbebọn to ji iya atọmọ gbe n beere l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Inu adura ni gbogbo awọn ọmọ ijọ Union Baptist Church, to wa ni Odi-Olówó, niluu Oṣogbo, wa bayii, latari ọkan lara wọn ti awọn agbebọn ji gbe.

Aago mẹfa irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, la gbọ pe awọn agbebọn ọhun ji Abilekọ Ọlayinka Tosin Kayọde ati ọmọ rẹ kan gbe lagbegbe Ọtaẹfun, si Kọbọngbogboẹ, niluu Oṣogbo.

Ṣọọbu la gbọ pe obinrin naa, to jẹ olukọ ewe ninu ijọ wọn ati ọmọ rẹ ti n bọ ki wọn too ko sọwọ awọn agbebọn ọhun.

Alufaa ijọ naa, Rẹfurẹndi (Dokita) Sunday Adediwura Adeoye, ṣalaye pe awọn agbebọn ọhun ti pe ọkọ obinrin naa, Ẹnjinnia Kayọde Abayọmi, pe ko san miliọnu marun-un Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ.

Wọn sọ fun ọkunrin naa pe inu akanti ileefowopamọ UBA to jẹ ti iyawo rẹ to wa nigbekun awọn ni ki wọn san owo ọhun si kiakia.

Dokita Adeoye waa ke si gbogbo awọn araalu lati rawọ ẹbẹ si Ọlọrun fun itusilẹ obinrin yii ati ọmọ rẹ layọ ati alaafia laipẹ rara.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ igbesẹ lati gba awọn mejeeji silẹ.

Leave a Reply