2023: Asiko ti to lati gba Naijiria lọwọ APC – Titi Abubakar

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Iyawo oludije funpo aarẹ orileede yii labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Oloye Titi Atiku, ti ke si gbogbo awọn obinrin nipinlẹ Ọṣun lati ṣiṣẹ pọ fun aṣeyọri ọkọ rẹ ninu idibo ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu keji ọdun yii.

Oloye Atiku to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ọṣun parọwa yii nibi eto kan l’Oṣogbo ti wọn pe ni “Ba awọn alaabagbe rẹ sọrọ lori foonu lati dibo fun Atiku”, eleyii ti Atiku Abubakar Development Agenda ṣonigbọwọ rẹ.

Nibi eto ti wọn ti pin kaadi ipe fun awọn obinrin ọhun ni Oloye Dupẹ Adeleke ti ṣoju iyawo oludije wọn, o si rọ awọn obinrin lati gba kaadi idibo wọn lati le dibo fun gbogbo awọn oludije ẹgbẹ PDP ninu idibo apapọ naa.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ọrọ ti mo ni fun awọn obinrin ni ki wọn bẹrẹ si i lọ kaakiri lati ba awọn iyalọja, awọn araadugbo atawọn ti wọn jọ n jọsin sọrọ lori idi ti wọn fi gbọdọ fi ibo wọn gbe Alhaji Atiku Abubakar ati Ifeanyi Okowa wọle”

“Ki wọn too le yan ẹni to wu wọn lọkan, wọn gbọdọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn lọdọ ajọ INEC, ki awọn ti wọn si ti gba a tọju rẹ daadaa titi di ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, nitori Alhaju Atiku nikan lo le gba wa ninu inira ti a n dojukọ lorileede yii.

Ninu ọrọ rẹ, Igbakeji alakooso eto naa, Olubunmi Alarape, ṣalaye pe kaadi ipe ti awọn pin fun awọn obinrin naa wa lati fi pe awọn araalu fun ipolongo awọn erongba rere ti Atiku ni fun wọn.

O ni pẹlu akori eto naa, awọn obinrin gbọdọ bọ sita, ki wọn maa ba awọn alajọgbe wọn sọrọ lori foonu nipa Atiku.

O ni, “Asiko ti to lati gba Naijiria lọwọ APC. Atiku nikan lo le gba Naijiria ninu wahala yii. A fẹ ẹ gba ogo Naijiria pada gẹgẹ bo ṣe wa nigba kan ri.

Leave a Reply