Miliọnu mẹrin owo alajẹṣẹku ti Salami lọọ ya lọmọ rẹ gbe sa lọ ni Ṣaki

Olu-Theo Omolohun Oke Ogun

Gbogbo isapa lawọn agbofinro ijọba ibilẹ Atisbo nipinlẹ Ọyọ n wa ọkunrin kan, Ọgbẹni Abiọla Salami, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, ati afẹsọna rẹ, Bọsẹ latari owo tuulu-tuulu ti iye rẹ jẹ miliọnu mẹrin naira, tawọn mejeeji si sa lọ, bẹẹ baba Abiọla, Oloye Ijiọla Salami, ẹni ọdun mẹtalelọgọrin, ni wọn lo lowo naa.

Ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii la gbọ pe iṣẹlẹ yii waye, nile baba naa to wa Irawo ile nilu naa.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Abiọla ni ọmọ kẹta ̀lọdọ iya rẹ nile baba naa, ṣugbọn iya rẹ ọhun ko ni ni Naijiria, ilu Yesude, lorileede olominira Togo loun n gbe.

Wọn ni ọjọ mẹta ṣaaju iṣẹlẹ yii ni afurasi ole yii de sọdọ baba naa, o loun mu afẹsọna rẹ, to jẹ ọmọ bibi ilu Ẹfọn Alaye, nipinlẹ Ekiti, waa ki baba naa, lati jẹ ki wọn mọ ẹni toun fẹẹ fẹ.

Wọn ni bi wọn ṣe de ni wọn ti fura pe baba naa n ṣowo kata-kara kan, ti wọn si ri i pe awọn kọsitọma rẹ n sanwo fun un, eyi lo mu ki wọn bẹrẹ si i fimu finlẹ lati mọ ibi to n tọju owo naa si.

Lọjọ tiṣẹlẹ yii waye, wọn ni baba naa lọ sipade ilu kan lọjọ naa ni, ko too dari de lọmọ rẹ ati afẹsọna rẹ ti ja agadagodo ti baba fi tilẹkun ẹ, wọn tu ile kan ibi to n kowo pamọ si, wọn si ji owo naa gbe sa lọ.

Nigba ti baba de, ṣiṣi silẹ gbayawu lo ba ilẹkun to ti pa ko too lọ, bo si ṣe wọle lo ri bi wọn ṣe ṣe inu yara rẹ yankanyankan, kia lo lọ sibi tọ tọju owo si, lowo ba ni ko rọra mu oun, ẹfọn ti fẹ, owo ti dawati.

Baba naa figbe bọnu, o ni owo awọn alajẹṣẹku toun lọọ ya lati fi ṣiṣẹ oko, ati kara-kata toun n ṣe lowo naa, oun si gbọdọ da a pada pẹlu ele, pe kawọn araadugbo gba oun.

Ọkan ninu awọn ti wọn jọ n gbele ni wọn ta a lolobo pe awọn ri ọmọ rẹ, Abiọla pẹlu afẹsọna rẹ, ti wọn wọle, eyi lo jẹ ki baba naa mọ ibi ti ina to jo oun ti wa, lo ba lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Tede.

Awọn ọlọpaa ti lọọ fọrọ wa ọlọkaada to gbe awọn afurasi ọdaran naa lẹnu wo, wọn si ṣeleri pe awari tobinrin n wa nnkan ọbẹ lawọn yoo fọrọ awọn firi nidii ọkẹ alọ-kolohun-kigbe yii ṣe. Bakan naa la gbọ pawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ kan ti n ṣiṣẹ lori ọrọ yii.

 

 

Virus-free. www.avast.com

Leave a Reply