Ibrahim Alagunmu, Ilorin.
Hon. Ọlamilekan Yusuf ti ọpọ eniyan mọ si Iyemọja, ti awọn ajinigbe ji gbe nile rẹ, ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti gba ominira lẹyin ọjọ mẹfa lahaamọ awọn ajinigbe.
Ọlamilekan ṣalaye fun ALAROYE pe nigba ti wọn n gbinyanju lati ji oun gbe ni wọn sa oun ladaa lori, ti ẹjẹ si n ṣan ni gbogbo ara oun. Ṣugbọn eyi ko tu irun kankan lara awọn ajinigbe yii nitori niṣe lawọn bẹrẹ irin, awọn si rin lati Mandi, n’Ilọrin, de ilu Malete, nijọba ibilẹ Moro. O ni lẹyin ti awọn de Molete, awọn tun mu irin pọn, awọn rin de Olooru, Olooru lo ni wọn ti ri oun mọlẹ, ti wọn ko si fun oun ni ounjẹ lati igba naa, ti oun si bẹrẹ si i jẹ kooko.
O tẹsiwaju pe kikidaa Fulani ni awọn ti wọn ji oun gbe, bẹẹ loun ko wọṣọ, toun ko si wẹ latigba ti oun ti wa laahamọ wọn.
Miliọnu mẹwaa naira lọkunrin naa ni awọn ajinigbe ọhun gba pẹlu owo ipe kaadi ẹgbẹrun mẹwaa naira, miliki katọọnu kan ati mọtina ni wọn gba ki wọn too tu u silẹ ni ahamọ.
Ni bayii Iyemọja ti n gba itọju nileewosan gẹnẹra ti ilu Ilọrin.