Mo kabaamọ pe mo gun iyawo mi pa nitori ọrọ foonu-Abubakar

Monisọla Saka

Ọwọ awọn agbofinro ipinlẹ Adamawa, ti tẹ Ibrahim Abubakar, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (33), nitori bo ṣe gun iyawo ẹ, Hajara Saadu, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25) yannayanna ti tiyẹn fi ku nitori foonu rẹ to ni o mu.

Ọkunrin afurasi alapata to n gbe niluu Sabon Gari-Futy, nijọba ibilẹ Girei, nipinlẹ naa, ni wọn lo gun oloogbe lọbẹ lẹyin laimọye igba, titi ti ẹmi fi bọ lara ẹ.

Ninu atẹjade ti SP Suleiman Yahaya Nguroje, ti i ṣe agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ naa fi sita lo ti sọ pe ni nnkan bii aago mẹrin aabọ idaji ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni Abubakar yọ ọbẹ siyawo ẹ, lẹyin to fẹsun kan an pe o mu foonu oun to si gun un ni gbogbo ara. Ọgbẹ nla nla ti ọbẹ naa da ati apọju ẹjẹ to ṣofo lara ẹ ni wọn lo ṣokunfa iku obinrin yii ki wọn too gbe e dele iwosan rara.

Baba oloogbe yii ni wọn lo lọọ fẹjọ ana ẹ sun ni teṣan ọlọpaa tọwọ fi tẹ ẹ. Lasiko iwadii ti wọn ṣe ni wọn ti ri nnkan ti afurasi lo lati fi gbẹmi iyawo rẹ ọhun.

Lasiko ifọrọwanilẹnuwo ni afurasi ti jẹwọ pe loootọ loun gun iyawo oun, to tun jẹ iya ọmọ kan ṣoṣo tawọn bi pa.

O loun kabaamọ pe iku obinrin naa tọwọ oun wa nitori ọrọ foonu to fa fa-n-fa laarin awọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti ni dandan ni ki afurasi jẹ iya to tọ si i ni kete tawọn ba ti pari iwadii.

 

Leave a Reply