Idigunjale lawọn eleyii fi n ṣe ankoo, kẹkẹ Marwa ni wọn maa n ja gba

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn ọlọpaa agbegbe Jimeta-Mubi, nipinlẹ Adamawa, ni awọn adigunjale ikọ ẹlẹni mẹrin kan ti wọn ti jingiri ninu jiji kẹkẹ Marwa awọn araalu ọhun gbe wa bayii, wọn si ti n ran awọn agbofinro lọwọ ninu iwadii wọn nipa ẹsun ti wọn fi kan wọn yii.

Awọn mẹrin ọhun ni Abdullah Yusuf, ẹni ọdun mejilelogun, Umar Yahaya, ẹni ogun ọdun, Hassan Ishaka, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ati Shuaibu Abubarkar, ẹni ọdun mọkandinlogun, ti gbogbo wọn pata n gbe lagbegbe Kwabura, nijọba ibilẹ Hawal, nipinlẹ Borno.

ALAROYE gbọ pe ṣe lawọn Afurasi ọdaran ọhun maa n ṣe bii ero to fẹẹ wọ kẹkẹ Marwa, lẹyin ti wọn ba wọle tan ni wọn maa ja kẹkẹ naa gba mọ ẹni to ni i lọwọ lasiko tiyẹn ba n gbe wọn lọ sibi ti wọn darukọ fun un.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Suleiman Nguroje, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ Aiku, Sanndee, ọjọ keje, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni awọn afurasi ọdaran ohun pe onikẹkẹ Marwa kan pe ko waa gbe awọn lọ sagbegbe Jimeta Mubi, ṣugbọn loju ọna ni wọn ti ti i bọ silẹ ninu kẹkẹ  rẹ lori ere, ti wọn si ji kẹkẹ naa gbe sa lọ.

Alukoro ni loju-ẹsẹ tawọn ti gba ipe pajawiri nipa iṣẹlẹ ọhun lawọn ti bẹrẹ si i ṣewadii, tawọn si pada fọwọ ofin mu awọn ọdaran ọhun, tawọn si tun gba Kẹkẹ Marwa naa lọwọ wọn.

Ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, C.P Dankombo Morris, ti fi da awọn araalu ọhun loju pe laipẹ yii lawọn maa too foju gbogbo wọn bale-ẹjọ, ki wọn le jiya ẹṣẹ wọn labẹ ofin.

 

Leave a Reply