Araalu meji padanu ẹmi wọn nibi ija agba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun

Adewale Adeoye

Ṣe lọrọ di bo o lọ o yago lasiko tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji kan doju ija kọra wọn lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keje, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, niluu kan ti wọn n pe ni Awka, nipinlẹ Anambra, tawọn araalu meji si ku iku ojiji.

ALAROYE gbọ pe eyi to waye lọsẹ yii bẹrẹ lasiko tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji kan n le ara wọn pẹlu Kẹkẹ Marwa, lagbegbe Ziks, niluu Eke Awka. Bi wọn ṣe koju ara wọn ni wọn ti yinbọn pa eni kan lara wọn.

Awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn sọ pe afi bii fiimu lọrọ ọhun jọ lọjọ naa, nitori pe ṣe ni wọn n fibọn le ara wọn kaakiri igberiko, ti wọn si n dọdẹ ara wọn. Gbaugbau ni wọn n yinbọn soke, ti awọn araalu si n sare akọlu-kọgba lọjọ naa. Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti wọn wa ninu Kẹkẹ Marwa to ṣaaju ni wọn n le lọ. Bi ina to n dari ọkọ lagbegbe naa ṣe da Kẹkẹ Marwa yii duro ni ọkan lara awọn to wa ninu rẹ ti sa bọ silẹ, to si n sa lọ lẹlẹ, ṣugbọn awọn alatako rẹ naa n sa tọ ọ lẹyin, bẹẹ ni kaluku wọn n yinbọn tẹle ara wọn.

Lopin ohun gbogbo, ọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n le ẹni to sa bọ silẹ ninu Kẹkẹ Marwa naa tẹ ẹ, wọn wọọ jade ninu ibi to sapamọ si, wọn si yinbọn pa a loju-ẹsẹ. Iṣẹlẹ ọhun lo mu ki idarudapọ waye lagbegbe naa, tawọn araalu si n sa asala fun ẹmi wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa S.P Tochukwu Ikenga ni oun ko ti gba ipe lori iṣẹlẹ ọhun.

 

Leave a Reply