O ṣẹlẹ, eyi nidi ti igbẹjọ Bobrisky ko fi waye mọ

Monisọla Saka

Gbajumọ ọkunrin bii obinrin nni, Idris Ọlanrewaju Okunẹyẹ, tawọn eeyan mọ si Bobrisky tabi Mummy of Lagos, ti wọ gau bayii, afaimọ si ni ọkunrin to ti fẹrẹ sọra ẹ dobinrin tan yii ko ni i ṣọdun itunu aawẹ latimọle.

Eyi waye latari isinmi ọdun tijọba apapọ kede jake-kado orilẹ-ede Naijiria.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lo yẹ ki igbẹjọ Bobrisky tun waye nile-ẹjọ giga ijọba apapọ, Federal High Court, to wa niluu Eko, amọ ti isinmi ọlọjọ mẹta ti yoo bẹrẹ lati ọjọ Tusidee titi di Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin yii, ti bẹgi dina rẹ.

Ṣaaju akoko yii, lọjọ karun-un, oṣu Kẹrin yii, ni wọn ti kọkọ foju Bobrisky bale ẹjọ, lẹyin to jọwọ ara rẹ fawọn ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹ-ede yii, iyẹn Economic and Financial Crimes Commission (EFCC).

Odidi ẹsun mẹfa ọtọọtọ ni ajọ EFCC ka si Bobrisky lọrun, eyi ti ṣiṣe owo Naira baṣubaṣu ati arọndarọnda owo jẹ ọkan lara ẹsun naa.

Tẹ o ba gbagbe, fidio ibi ti Bobrisky ti n nawo, to n fọn ọn, ti wọn si n tẹ ẹ mọlẹ baṣubaṣu nibi ayẹyẹ afihan fiimu Ajakaju, to waye ni gbọngan Circle Mall, Jakande, Lẹkki, nipinlẹ Eko, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, lo jẹ olori ohun to ṣakoba fun ọkunrin bii obinrin yii, gẹgẹ bi Agbefọba, Suleiman Suleiman, ṣe sọ niwaju Onidaajọ Abimbọla Awogbọrọ.

Owo to to ẹgbẹrun lọna irinwo Naira (400,000), ni EFCC sọ pe Bobrisky n fọn lasiko to n jo nibi ayẹyẹ naa. Bakan naa ni wọn fi kun un pe aimọye owo Naira ni Bobrisky ti ṣe baṣubaṣu laarin ọdun 2022 si 2023, lawọn ode ariya kaakiri.

Ẹsun ti wọn ka si Idris lọrun yii ni wọn lo ta ko ofin banki apapọ ilẹ wa, (CBN), ti ọdun 2007, ati ti eyi to ta ko arọndarọnda owo (Money Laundering), ti ọdun 2022.

Bobrisky to bẹbẹ lẹyin to loun gba pe oun jẹbi ẹsun mẹrin akọkọ ti wọn fi kan an sọ pe ki ile-ẹjọ ṣiju aanu wo oun, nitori oun ko mọ pe aidaa ni nnkan ti oun ṣe.

Bakan naa lo tun ṣeleri pe tile-ẹjọ ba le gba ẹbẹ oun, oun yoo lo ipo ati gbogbo ikanni ayelujara oun lati polongo ta ko ṣiṣe owo Naira baṣubaṣu.

Bo tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ da a lẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an yii, ti wọn si sun ẹjọ mi-in si ọjọ kẹsan-an, oṣu yii, afi ki wọn kede ọjọ igbẹjọ tuntun, niwọn igba ti isinmi ọdun tijọba kede ti bọ si ọjọ ti kootu fi igbẹjọ rẹ si tẹlẹ.

Leave a Reply